Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Kọ́ Àwọn Òbí Àtàwọn Ọmọ Nítorí Àwọn Tó Ń Bá Ọmọdé Ṣèṣekúṣe

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Kọ́ Àwọn Òbí Àtàwọn Ọmọ Nítorí Àwọn Tó Ń Bá Ọmọdé Ṣèṣekúṣe

Bíbélì rọ àwọn òbí pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n dáàbò bò wọ́n, kí wọ́n máa tọ́ wọn sọ́nà, kí wọ́n sì mọ̀ pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n. (Sáàmù 127:3; Òwe 1:8; Éfésù 6:1-4) Ọ̀kan lára àwọn ohun tó lè wu ọmọ léwu ni àwọn tó máa ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe. Torí náà, ó yẹ káwọn òbí dáàbò bo àwọn ọmọ wọn kí wọ́n má bàa kó sọ́wọ́ irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀.

Ọ̀pọ̀ ọdún làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń tẹ àwọn ìwé tó ń jẹ́ káwọn tó wà nínú ìdílé ṣe ara wọn lọ́kan. Yàtọ̀ síyẹn, a ti ṣe àwọn ìwé tó ń ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ àwọn tó ń bá ọmọdé ṣèṣekúṣe àti bí àwọn ọmọ náà ṣe lè dá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ mọ̀. Díẹ̀ lára àwọn ìwé táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tẹ̀ jáde ló wà nísàlẹ̀ yìí. Àwọn àpilẹ̀kọ náà fún wa láwọn ìsọfúnni pàtó lórí àwọn ọ̀rọ̀ yìí. Ẹ kíyè sí iye ẹ̀dà tá a tẹ̀ jáde àti iye èdè tá a tú àwọn àpilẹ̀kọ náà sí.

 • Àkòrí: Ibalopọ̀ Takọ-tabo Laaarin Ibatan—Iwa Ọdaran Ti O Farasin

  • Ìtẹ̀jáde: Jí! April 8, 1982

  • Ẹ̀dà: 7,800,000

  • Èdè: 34

 • Àkòrí: Iranlowo fun Awọn Ẹran-ijẹ Ibalopọ Takọtabo Laarin Ibatan

  • Ìtẹ̀jáde: Ilé Ìṣọ́ April 1, 1984

  • Ẹ̀dà: 10,050,000

  • Èdè: 102

 • Àkòrí: Ìfìtínà Ọmọdé—Àlá Buburu fun Gbogbo Iya; Ìfìtínà Ọmọdé—Tani Yoo Ṣe Iru Nkan Bẹẹ?’; Ìfìtínà Ọmọdé—Iwọ Lè Daabo Bo Ọmọ Rẹ

  • Ìtẹ̀jáde: Jí! July 22, 1986

  • Ẹ̀dà: 9,800,000

  • Èdè: 54

 • Àkòrí: Awọn Òjìyà Ipalara Aláìmọwọ́mẹsẹ̀ ti Ìlòkulò Ọmọdé; Awọn Ọgbẹ́ Fifarasin ti Lilo Ọmọde Nílòkulò

  • Ìtẹ̀jáde: Jí! March 8, 1992

  • Ẹ̀dà: 12,980,000

  • Èdè: 64

 • Àkòrí: Ọmọ Rẹ Wà Ninu Ewu!; Bawo Ni A Ṣe Lè Dáàbò Bo Awọn Ọmọ Wa?; Ìdènà Ninu Ilé

  • Ìtẹ̀jáde: Jí! October 8, 1993

  • Ẹ̀dà: 13,240,000

  • Èdè: 67

 • Àkòrí: Protect Your Children

  • Ìtẹ̀jáde: Public Service Announcement Video Number 4, tá a ṣe jáde lọ́dún 2002

  • Èdè: 2

 • Àkòrí: Bí Ọlọ́run Ṣe Dáàbò Bo Jésù

 • Àkòrí: Ewu Tí Gbogbo Òbí Ń Kọminú Lé Lórí; Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Yín; Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Mú Kí Ilé Yín Jẹ́ Ibi Ààbò

  • Ìtẹ̀jáde: Jí! October 2007

  • Ẹ̀dà: 34,267,000

  • Èdè: 81

 • Àkòrí: Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Kó Sọ́wọ́ Àwọn Tó Ń Fipá Báni Lò Pọ̀?; Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Òbí Ń Béèrè: Ṣé Ó Yẹ Kí N Bá Ọmọ Mi Sọ̀rọ̀ Nípa Ìbálòpọ̀?

 • Àkòrí: Báwo Ni Àwọn Òbí Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Ọmọ Wọn Nípa Ìbálòpọ̀?

  • Ìtẹ̀jáde: Ìkànnì jw.org; àpilẹ̀kọ kan tó jáde ní September 5, 2013

  • Èdè: 64

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà á ṣì máa kọ́ àwọn òbí àtàwọn ọmọ káwọn ọmọ náà má bàa kó sọ́wọ́ àwọn tó ń bá ọmọdé ṣèṣekúṣe.