Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Fipá Mú Káwọn Èèyàn Yí Ẹ̀sìn Wọn Pa Dà?

Ṣé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Fipá Mú Káwọn Èèyàn Yí Ẹ̀sìn Wọn Pa Dà?

 Rárá, a kì í ṣe bẹ́ẹ̀. A ti sọ ọ́ rí nínú ìwé tá à ń tẹ̀ jáde jù, ìyẹn Ilé Ìṣọ́, pé: “Fífi agbára mú kí àwọn èèyàn yí ẹ̀sìn wọn padà jẹ́ ohun tó lòdì.” a Ohun tí kì í jẹ́ ká fipá mú àwọn èèyàn ni pé:

  •   Jésù ò fipá mú àwọn èèyàn rí pé kí wọ́n gba ohun tóun ń kọ́ wọn. Ó mọ̀ pé àwọn tó máa gbọ́ tòun ò lè pọ̀. (Mátíù 7:​13, 14) Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kan ò fara mọ́ ohun tó sọ, tí wọ́n sì fẹ́ fi í sílẹ̀, dípò kó fipá mú kí wọ́n dúró, ṣe ló fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa lọ.​—Jòhánù 6:​60-​62, 66-​68.

  •   Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n má fipá mú àwọn èèyàn yí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ pa dà. Ó ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa wá àwọn tó ṣe tán àtigbọ́ ọ̀rọ̀ wọn dípò kí wọ́n máa fipá mú káwọn èèyàn gbọ́ ìròyìn ayọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run, tó sì jẹ́ pé kò wù wọ́n gbọ́.​—Mátíù 10:​7, 11-​14.

  •   Tí wọ́n bá fipá mú kẹ́nì kan yí ẹ̀sìn rẹ̀ pa dà, bí ẹni yín àgbàdo sẹ́yìn igbá ni, torí ìjọsìn téèyàn bá ṣe látọkàn wá nìkan ni Ọlọ́run máa ń tẹ́wọ́ gbà.​—Diutarónómì 6:​4, 5; Mátíù 22:37, 38.

Ṣé torí àtiyí àwọn èèyàn lẹ́sìn pa dà la ṣe ń wàásù?

 Òótọ́ ni pé à ń sọ ohun tó wà nínú Bíbélì fáwọn èèyàn “dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé,” a sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípa kíkọ́ni “ní gbangba àti láti ilé dé ilé,” bí Bíbélì ṣe pa á láṣẹ. (Ìṣe 1:8; 10:42; 20:20) Àmọ́ nígbà míì, àwọn èèyàn máa ń fẹ̀sùn kàn wá bíi tàwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ pé à ń yí àwọn èèyàn lẹ́sìn pa dà lọ́nà tí ò bófin mu. (Ìṣe 18:12, 13) Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá, ẹ̀sùn èké ni. A kì í fipá mú ẹnikẹ́ni pé kó gba ohun tá a gbà gbọ́. Dípò ìyẹn, ṣe la máa ń fẹ́ káwọn èèyàn kẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè ní ìmọ̀, kí wọ́n wá pinnu ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe.

 A kì í fipá mú káwọn èèyàn yí ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe pa dà, bẹ́ẹ̀ la kì í lọ́wọ́ sí òṣèlú lórúkọ ẹ̀sìn, a kì í sì í fi owó, ohun ìní tàbí àwọn nǹkan míì fa ojú àwọn èèyàn mọ́ra kí wọ́n lè máa ṣe ẹ̀sìn wa. Ohun táwọn kan tí wọ́n ń pera wọn ní Kristẹni ń ṣe nìyẹn, ṣe nìyẹn ń tàbùkù sí Kristi. b

Ṣé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti yí ẹ̀sìn tó ń ṣe pa dà?

Wòlíì Ábúráhámù ò ṣe ẹ̀sìn táwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ń ṣe

 Bẹ́ẹ̀ ni, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti yí ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe pa dà. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀ àwọn tí ò ṣe ẹ̀sìn táwọn mọ̀lẹ́bí wọn ń ṣe, tí wọ́n sì fúnra wọn pinnu pé Ọlọ́run tòótọ́ làwọn á máa sìn. Díẹ̀ lára wọn ni Ábúráhámù, Rúùtù, àwọn ará Áténì àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. (Jóṣúà 24:2; Rúùtù 1:​14-​16; Ìṣe 17:22, 30-​34; Gálátíà 1:​14, 23) Bíbélì tiẹ̀ tún sọ pé ẹni tó ti ń sin Ọlọ́run lọ́nà tó fọwọ́ sí lè yàn pé òun ò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìpinnu tí ò dáa nìyẹn.​—1 Jòhánù 2:​19.

 Ìwé òfin tó ń polongo ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn táwọn èèyàn ní kárí ayé, ìyẹn Universal Declaration of Human Rights fọwọ́ sí i pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti yí ẹ̀sìn tó ń ṣe pa dà. Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè sọ pé orí ìwé yìí ni òfin ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àwọn èèyàn lágbàáyé dá lé. Ìwé yìí sọ pé gbogbo èèyàn ló ní “òmìnira láti yí ẹ̀sìn rẹ̀ tàbí ohun tó gbà gbọ́ pa dà,” tó sì lè “wá ìsọfúnni, kó gbà á, kó sì sọ ọ́ fún ẹlòmíì,” èyí ò sì yọ ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn sílẹ̀. c Kì í ṣe pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe àwọn nǹkan yìí nìkan ni, èèyàn tún gbọ́dọ̀ mọ̀ pé àwọn míì náà lẹ́tọ̀ọ́ láti rọ̀ mọ́ ohun tí wọ́n gbà gbọ́, kí wọ́n sì ta ko ohun tí wọn ò bá fara mọ́.

Téèyàn bá yí ẹ̀sìn pa dà, ṣó ti dalẹ̀ ẹbí àtàwọn aráàlú ẹ̀ nìyẹn?

 Kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀. Bíbélì ní ká máa bọ̀wọ̀ fún gbogbo èèyàn, láìka ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe sí. (1 Pétérù 2:​17) Bákan náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tẹ̀ lé àṣẹ tí Bíbélì pa pé ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wa, bí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ bá tiẹ̀ yàtọ̀ sí tiwa.​—Éfésù 6:​2, 3.

 Síbẹ̀, gbogbo èèyàn kọ́ ló gba ohun tí Bíbélì sọ yìí. Obìnrin kan tó dàgbà sí orílẹ̀-èdè Zambia sọ pé: “Níbi tí mo dàgbà sí, àwọn èèyàn ka ẹni tó bá yí ẹ̀sìn rẹ̀ pa dà . . . sí aláìṣòótọ́, wọ́n ló ti dalẹ̀ ẹbí àtàwọn aráàlú rẹ̀.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí obìnrin yìí náà nìyẹn nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tóun náà sì wá pinnu pé òun máa yí ẹ̀sìn pa dà. Ó ní: “Ṣe làwọn òbí mi ń ránnu mọ́ ọn pé inú àwọn ò dùn sí mi rárá pẹ̀lú ohun tí mo ṣe yìí, wọ́n ní mo já àwọn kulẹ̀. Kò rọrùn fún mi rárá, torí mi ò kóyán àwọn òbí mi kéré. . . . Mo pinnu pé Jèhófà ni màá dúró tì, mi ò ní lọ́wọ́ sí àṣà tí wọ́n ń ṣe nínú ẹ̀sìn àwọn mọ̀lẹ́bí mi. Àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé mo dalẹ̀ àwọn ẹbí mi.” d

a Wo Ilé Ìṣọ́ January 1, 2002, ojú ìwé 12, ìpínrọ̀ 15.

b Bí àpẹẹrẹ, ní nǹkan bíi 785 S.K., Charlemagne ṣòfin pé ṣe ni wọ́n á pa gbogbo àwọn tó bá kọ̀ láti di Kristẹni nílùú Saxony. Bákan náà, lọ́dún 1555 S.K, àwọn olórí Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́ tó ń bára wọn jà tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn tí wọ́n pè ní Peace of Augsburg, tó sọ pé ẹni tó bá fẹ́ jọba gbọ́dọ̀ jẹ́ Kátólíìkì tàbí ọmọ ẹ̀yìn Luther, ẹ̀sìn kan náà sì ni kí gbogbo àwọn tó bá wà lábẹ́ rẹ̀ máa ṣe. Wọ́n ní kí gbogbo àwọn tí kò bá fara mọ́ ọn kúrò nílùú.

c Àwọn ìwé òfin míì náà fọwọ́ sí i pé èèyàn ní ẹ̀tọ́ yìí. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tí ilẹ̀ Áfíríkà, ìyẹn African Charter on Human and Peoples’ Rights, ìwé ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tí ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ìyẹn American Declaration of the Rights and Duties of Man, ìwé ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ti ilẹ̀ Arébíà tí wọ́n ṣe lọ́dún 2004, ìyẹn Arab Charter on Human Rights, ìwé ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ti ilẹ̀ Éṣíà, ìyẹn ASEAN (Association of Southeast Asian Nations) Human Rights Declaration, ìwé ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn European Convention on Human Rights, àti ìwé àdéhùn International Covenant on Civil and Political Rights. Àwọn orílẹ̀-èdè kan tí fọwọ́ sí àwọn ìwé òfin yìí, wọ́n sì sọ pé àwọn ń tẹ̀ lé e, àmọ́ ọwọ́ tí kálukú wọn fi mú un yàtọ̀ síra.

d Bíbélì fi hàn pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run tòótọ́.