Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Ẹ Ní Àwọn Àlùfáà Tí Ẹ̀ Ń Sanwó Fún?

Ṣé Ẹ Ní Àwọn Àlùfáà Tí Ẹ̀ Ń Sanwó Fún?

 Àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé, a kì í ní ẹgbẹ́ àlùfáà àti ti ọmọ ìjọ. Gbogbo àwọn ará wa tó ti ṣe ìrìbọmi jẹ́ òjíṣẹ́ tó máa ń wàásù, tí wọ́n sì ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. A máa ń pín àwọn ará sínú ìjọ tó máa ń ní nǹkan bí èèyàn ọgọ́rùn-ún [100]. Àwọn ọkùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn tó wà ní ìjọ kọ̀ọ̀kan ló máa ń sìn gẹ́gẹ́ bí “àgbà ọkùnrin,” tàbí àwọn alàgbà. (Títù 1:5) Wọn kì í sì í gbowó iṣẹ́.