Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Fipá Mú Káwọn Ọmọ Wọn Ṣe Ẹ̀sìn Wọn?

Ṣé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Fipá Mú Káwọn Ọmọ Wọn Ṣe Ẹ̀sìn Wọn?

 Rárá o, torí pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bóyá òun fẹ́ sin Ọlọ́run tàbí òun ò sìn ín. (Róòmù 14:12) Àtikékeré làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn láwọn ìlànà Bíbélì, àmọ́ táwọn ọmọ náà bá ti dàgbà, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló máa pinnu bóyá kóun di Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí kò má dì í.​—⁠Róòmù 12:2; Gálátíà 6:⁠5.

 Ó wu àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé káwọn ọmọ wọn gbé ìgbé ayé tó dáa, ohun tí ọ̀pọ̀ òbí sì ń fẹ́ fáwọn ọmọ wọn náà nìyẹn. Ohun tí wọ́n gbà pé ó máa ṣe àwọn ọmọ wọn láǹfààní ni wọ́n fi ń kọ́ wọn, ìyẹn ẹ̀kọ́ ilé, àwọn ìlànà ìwà rere àtàwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé Bíbélì nìkan ló lè mú kéèyàn gbé ìgbé ayé tó dáa jù lọ. Kí wọ́n ba lè gbin kókó yìí sáwọn ọmọ wọn lọ́kàn, wọ́n máa ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì jọ máa ń lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni. (Diutarónómì 6:​6, 7) Tí ọmọ kọ̀ọ̀kan bá dàgbà, ó máa pinnu bóyá kóun ṣe ẹ̀sìn àwọn òbí òun tàbí kó má ṣe bẹ́ẹ̀.

 Ṣé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣèrìbọmi fáwọn ọmọ ọwọ́?

 Rárá o. Bíbélì ò fọwọ́ sí i pé ká ṣèrìbọmi fáwọn ọmọ ọwọ́. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì fi kọ́ni pé káwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tó ṣèrìbọmi, wọ́n wàásù fún wọn, wọ́n “fi ayọ̀ gba” ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì ronú pìwàdà. (Ìṣe 2:​14, 22, 38, 41) Torí náà, kéèyàn tó lè ṣèrìbọmi, ó gbọ́dọ̀ dàgbà débi tó fi máa lóye ohun tí Bíbélì fi kọ́ni, ó gbọ́dọ̀ gbà á gbọ́, ó sì gbọ́dọ̀ pinnu pé òun á máa fi ohun tóun kọ́ sílò nígbèésí ayé òun. Àwọn ọmọ ọwọ́ ò sì lè ṣàwọn nǹkan yìí.

 Báwọn ọmọ náà ṣe ń dàgbà sí i, wọ́n lè pinnu pé àwọn máa ṣèrìbọmi. Àmọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ lóye ohun tí àdéhùn tí wọ́n fẹ́ ṣe túmọ̀ sí.

 Ṣé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pa àwọn ọmọ wọn tì tí wọ́n bá kọ̀ láti ṣèrìbọmi?

 Rárá o. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú àwọn òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í dùn táwọn ọmọ wọn ò bá ṣe ẹ̀sìn wọn, àmọ́ wọ́n ṣì máa ń nífẹ̀ẹ́ ọmọ wọn, wọn ò kì í jẹ́ kíyẹn ba àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú àwọn ọmọ jẹ́ torí pé ọmọ náà kọ̀ láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Láìka ọjọ́ orí wa sí, ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bóyá òun máa ṣèrìbọmi tàbí òun ò ní ṣe bẹ́ẹ̀

 Kí nìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń mú àwọn ọmọ wọn dání tí wọ́n bá ń wàásù?

 Ohun mélòó kan ló fà á tá a fi ń mu àwọn ọmọ wa dání nígbà tá a bá ń wàásù. a

  •   Bíbélì pàṣẹ fáwọn òbí pé kí wọ́n kọ́ àwọn ọmọ nípa Ọlọ́run kí wọ́n sì kọ́ wọ́n láti sin ín. (Éfésù 6:⁠4) Torí pé téèyàn bá fẹ́ sin Ọlọ́run, ó gba pé kẹ́ni náà sọ ohun tó gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì, ìdí nìyẹn tí iṣẹ́ ìwàásù fi jẹ́ ọ̀nà pàtàkì táwọn òbí fi lè kọ́ ọmọ wọn nípa Ọlọ́run.​—Róòmù 10:9, 10; Hébérù 13:15.

  •   Bíbélì dìídì gba àwọn ọmọdé níyànjú pé kí “wọn kí ó máa yin orúkọ Olúwa.” (Sáàmù 148:​12, 13, Bíbélì Mímọ́) Ọ̀nà tó dára jù láti yin Ọlọ́run ni pé kéèyàn sọ̀rọ̀ rẹ̀ fáwọn míì. b

  •   Ọ̀pọ̀ àǹfààní làwọn ọmọdé máa ń rí tí wọ́n bá ń wàásù pẹ̀lú àwọn òbí wọn. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń kọ́ bí wọ́n ṣe lè bá onírúurú èèyàn sọ̀rọ̀, wọ́n sì máa ń kọ́ bí wọ́n ṣe lè ní àwọn ànímọ́ tó ṣeyebíye bí àánú, inú rere, ọ̀wọ̀, àti kéèyàn má ṣe jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan. Iṣẹ́ ìwàásù tún máa ń jẹ́ káwọn ọmọdé túbọ̀ lóye àwọn bí Bíbélì ṣe ti ohun tí wọ́n gbà gbọ́ lẹ́yìn.

 Ṣé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe àwọn ayẹyẹ àtàwọn ọdún míì?

 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe àwọn ayẹyẹ tàbí àwọn ọdún tí inú Ọlọ́run kò dùn sí. c (2 Kọ́ríńtì 6:​14-17; Éfésù 5:10) Bí àpẹẹrẹ, a kì í ṣe àwọn ayẹyẹ tí Bíbélì ò fọwọ́ sí, bí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí tàbí ọdún Kérésìmesì.

 Bó ti wù kó rí, a máa ń lo àkókò pẹ̀lú ìdílé wa, a sì máa ń fáwọn ọmọ wa lẹ́bùn. Dípò ká máa dúró dé ọjọ́ kan pàtó nínú ọdún ká tó wà papọ̀, ká sì tó lè fún ara wa lẹ́bùn, a máa ń kó ara wa lẹ́nu jọ, a sì máa ń fúnra wa lẹ́bùn jálẹ̀ ọdún.

Inú àwọn òbí Kristẹni máa ń dùn láti máa fún àwọn ọmọ wọn lẹ́bùn

a Kárí ayé, a ò kì í gba àwọn ọmọdé tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyè láti dá nìkan wàásù àfi táwọn òbí wọn tàbí ẹlòmíì tó ti dàgbà bá wà pẹ̀lú wọn.

b Bíbélì mẹ́nu kan ọ̀pọ̀ ọmọdé tó múnú Ọlọ́run dùn torí pé wọ́n sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn èèyàn.—2 Ọba 5:1-3; Mátíù 21:15, 16; Lúùkù 2:42, 46, 47.

d A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.