Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Ṣe Àmúlùmálà Ìgbàgbọ́?

Ṣé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Ṣe Àmúlùmálà Ìgbàgbọ́?

 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gbádùn ká máa sọ ohun tá a gbà gbọ́ fáwọn èèyàn, láìka ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe sí, àmọ́ a kì í ṣe àmúlùmálà ìgbàgbọ́, ní ti pé a kì í bá àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn míì jọ́sìn. Bíbélì sọ pé àwọn Kristẹni tòótọ́ so “pọ̀ ní ìṣọ̀kan,” ohun pàtàkì kan tó sì so wọ́n pọ̀ ni ohun kan náà tí gbogbo wọn gbà gbọ́. (Éfésù 4:​16; 1 Kọ́ríńtì 1:​10; Fílípì 2:2) Ó ju ká kàn gbà pé ó yẹ ká máa nífẹ̀ẹ́ ara wa, ká yọ́nú síra wa, ká sì máa dárí ji ara wa. Ìmọ̀ tó péye látinú Bíbélì la gbé àwọn ohun tá a gbà gbọ́ kà, tá a bá sì yọwọ́ Bíbélì kúrò níbẹ̀, asán ni ohunkóhun tá a bá gbà gbọ́.​—Róòmù 10:​2, 3.

 Bíbélì sọ pé téèyàn bá ń bá àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn míì jọ́sìn, ṣe ló dà bí ẹni so ohun méjì tí kò dọ́gba pọ̀. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sì lè ba ìgbàgbọ́ Kristẹni jẹ́. (2 Kọ́ríńtì 6:​14-​17) Ìdí nìyẹn tí Jésú fi ní kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ má ṣe àmúlùmálà. (Mátíù 12:30; Jòhánù 14:6) Bákan náà, Ọlọ́run gbẹnu Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ pé kí wọ́n má ṣe bá àwọn aládùúgbò wọn jọ́sìn. (Ẹ́kísódù 34:11-​14) Nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ò gbà kí àwọn ẹlẹ́sìn míì wá ràn wọ́n lọ́wọ́, torí ṣe ni wọn ì bá da ẹ̀sìn pọ̀ níbi tí wọ́n ti jọ ń ṣiṣẹ́.​—Ẹ́sírà 4:​1-3.

Ṣé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń bá àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn míì sọ̀rọ̀?

 Bẹ́ẹ̀ ni. Kódà, lọ́dún 2023, wákàtí 1,791,490,713, èyí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù méjì wákàtí, la fi bá àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn míì sọ̀rọ̀. Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó máa ń wù wá ká mọ ohun tí “àwọn ènìyàn púpọ̀ jù lọ” ń rò àti ohun tí wọ́n gbà gbọ́ tá a bá lọ wàásù fún wọn. (1 Kọ́ríńtì 9:​19-​22) Tá a bá ń bá àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn míì sọ̀rọ̀, a máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé ká máa fi “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” wọ àwọn míì.​—1 Pétérù 3:​15.