Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tako Gbígba Abẹ́rẹ́ Àjẹsára?

Ṣé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tako Gbígba Abẹ́rẹ́ Àjẹsára?

 Rárá. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò tako gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára. A gbà pé Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bóyá kóun gba abẹ́rẹ́ àjẹsára tàbí kóun má ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ti pinnu láti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára.

 Tá a bá ń ṣàìsàn, a máa ń wá ibi tí wọ́n ti lè tọ́jú wa lọ́nà tó dáa. Inú wa sì ń dùn sí ìtẹ̀síwájú tó ń bá ìmọ̀ ìṣègùn. A tún mọyì àwọn dókítà àtàwọn elétò ìlera nítorí iṣẹ́ àṣekára tí wọ́n ń ṣe, pàápàá nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀.

 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ìlera. Bí àpẹẹrẹ, látìgbà tí àrùn Corona ti bẹ̀rẹ̀ làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń gbé onírúurú ìsọfúnni jáde ní ọ̀pọ̀ èdè sórí ìkànnì yìí, a sì ń rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n tẹ̀ lé ìtọ́ni tí ìjọba gbé kalẹ̀ lórí bá a ṣe lè dáàbò bo ara wa. Lára àwọn ìtọ́ni tí wọ́n fún wa ni pé, ká máa jìnnà síra, ká má kọjá iye tí wọ́n sọ pé ó lè péjọ síbì kan, ká máa ya ara wa sọ́tọ̀ tá a bá rí i pé a ní àrùn, ká máa fọ ọwọ́ wa, ká máa wọ ìbòmú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.—Róòmù 13:1, 2.

 Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn ìtẹ̀jáde awa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń tẹnu mọ́ àwọn ìlànà yìí:

  •   Kálukú ló máa pinnu ohun tó máa ṣe tó bá kan ọ̀rọ̀ ìlera.—Gálátíà 6:5.

     “[Ìwé Ìròyìn yìí] kò dámọ̀ràn àpẹẹrẹ-irú ìṣègùn tabi ìtọ́jú-ìwòsàn-ìṣègùn kan lékè òmíràn bẹẹni kò sì nawọ́ ìṣíníyè oniṣègun síni. Ìfojúsùn rẹ̀ wulẹ̀ jẹ́ lati mú awọn òtítọ́-ìṣẹ̀lẹ̀ jáde kí a sì fi í silẹ fún òǹkàwé náà lati gbé awọn nńkan yẹ̀wò kí ó sì ṣe ìpinnu ara rẹ̀.”—Jí!, February 8, 1987.

     “Ìwọ lo máa pinnu bóyá ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ máa gba abẹ́rẹ́ àjẹsára tàbí ẹ ò ní ṣe bẹ́ẹ̀.”—Jí!, August 22, 1965.

  •   A ma ń wá ìtọ́jú tó dáa torí pé ẹ̀mí ṣe pàtàkì sí wa.—Ìṣe 17:28.

     “Awọn Ẹlẹri Jehofah nṣe itọju ara wọn nipasẹ oriṣiriṣi ọgbọn iṣegun ti o le ran wọn lọwọ ninu iṣoro ilera wọn. Nwọn fẹran ìyè bẹni nwọn si nfẹ lati ṣe ohunkohun ti o ba le ṣeṣe ti o ba ọgbọn mu ti o si ba Iwe Mimọ mu pẹlu lati mu iwalaye wọn gun.”—Ilé Ìṣọ́, July 1, 1975.

     “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gba ìtọ́jú àti oògùn nílé ìwòsàn. Wọ́n fẹ́ kí ara wọ́n le, wọ́n sì ń fẹ́ kí ẹ̀mí àwọn gùn. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, Kristẹni kan wà tó ń jẹ́ Lúùkù, dókítà ni, bákan náà lónìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wà tí wọ́n jẹ́ dókítà. . . . Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọyì iṣẹ́ bàǹtàbanta táwọn dókítà ń ṣe láti tọ́jú àwọn èèyàn. Wọ́n sì tún ń fi ìmoore hàn fún bí wọ́n ṣe ń mú ìtura bá àwọn aláìsàn.”—Ilé Ìṣọ́, February 1, 2011.