Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Là Ń Pè Ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

Kí Là Ń Pè Ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbi tí a ti máa ń dáhùn ọ̀pọ̀ ìbéèrè, irú bí i:

  • Ta ni Ọlọ́run?

  • Ǹjẹ́ Ọlọ́run bìkítà nípa mi?

  • Báwo ni mo ṣe lè mú kí ìgbéyàwó mi dára sí i?

  • Báwo ni mo ṣe lè láyọ̀?

Nísàlẹ̀ yìí wàá rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tí àwọn èèyàn máa ń béèrè nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Báwo lẹ ṣe máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà? A máa ń mú kókó kan, irú bí “Ọlọ́run” tàbí “ìgbéyàwó,” a sì máa ń gbé àwọn ẹsẹ Bíbélì oríṣiríṣi tó bá sọ̀rọ̀ lórí kókó náà yẹ̀ wò. Tí a bá fi wọ́n wéra, a máa rí ohun tí Bíbélì sọ nípa kókó náà, nípa báyìí à ń jẹ́ kí Bíbélì ṣàlàyé ara rẹ̀.

A máa ń lo ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìwé yìí ṣàlàyé ọ̀pọ̀ nǹkan lọ́nà tó sẹ kedere títí kan ohun tí Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run, Jésù àti ọjọ́ ọ̀la wa.

Èló lẹ̀ ń gbà láti kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ọ̀fẹ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a kì í sì í díye lé ìwé tá à ń lò láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́.

Báwo ni àkókò tẹ́ ẹ fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ṣe máa ń gùn tó? Ọ̀pọ̀ máa ń ya nǹkan bí i wákàtí kan sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ká a lè jọ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ a lè fi kún àkókò náà tàbí kí a dín in kù. Àkókò tó o bá lè yà sọ́tọ̀ la máa lò.

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tí mo bá béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Tó o bá béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa wá bẹ̀ ẹ́ wò lákòókò tó o fẹ́ àti níbi tó rọrùn fún ẹ. Onítọ̀hún máa lo ìṣẹ́jú mélòó kan láti fi bí a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn ẹ́. Bí o bá nífẹ̀ẹ́ sí, o lè máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ.

Bí mo bá gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣe mo gbọ́dọ̀ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Rárá. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ láti máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ a kì í fipá mú ẹnikẹ́ni láti wọ ẹ̀sìn wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, a máa ń fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ ohun tó wà nínú Bíbélì fún àwọn èèyàn, torí a gbà pé kálukú ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó máa gbà gbọ́.—1 Pétérù 3:15.