Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

© Kim, Hyun-tae/iNaturalist. Licensed under CC-BY-4.0

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Ọ̀nà Àrà Táwọn Ọ̀pọ̀lọ́ Japanese Tree Ń Gbà Pe Ara Wọn

Ọ̀nà Àrà Táwọn Ọ̀pọ̀lọ́ Japanese Tree Ń Gbà Pe Ara Wọn

 A mọ̀ pé àwọn akọ ọ̀pọ̀lọ́ Japanese Tree máa ń pariwo ṣáá. Àmọ́ ohùn akọ kọ̀ọ̀kan dá yàtọ̀ láàárín agbo wọn. Ní Japan àwọn tó ń ṣe ìwádìí nípa ọ̀pọ̀lọ́ rí i pé, àṣírí ẹwà àwọn akọ ni bí wọ́n ṣe ń pe abo lọ́nà àrà tí ò fi ní sí ìkọlùkọgbà bí wọ́n bá tiẹ̀ wà lójú kan náà.

 Rò ó wò ná: Oríṣiríṣi ni ìró ohùn tí àwọn akọ ọ̀pọ̀lọ́ Japanese Tree fi ń fa ojú abo mọ́ra, ọ̀fun wọn ni ohùn yìí ti máa ń jáde ó sì máa ń rinlẹ̀ gan-an. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan nínú wọn máa ń han, súfèé tàbí dún bí ìgbà tí èèyàn bá ń han-run, èyí sinmi lórí irú akọ ọ̀pọ̀lọ́ tó jẹ́.

 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé oríṣiríṣi ọ̀pọ̀lọ́ ló wà, báwo la ṣe lè dá ohùn akọ ọ̀pọ̀lọ́ kan mọ̀ yàtọ̀? Dípò kí gbogbo wọn máa ké jáde lẹ́ẹ̀kan náà, ṣe ni wọ́n máa ń dánu dúró fúnra wọn bí ìwádìí ṣe sọ. Lọ́nà yìí ohùn wọn kì í kọlu ra ó sì máa ń já geere, bẹ́ẹ̀ ni kì í jẹ́ kó tètè rẹ̀ wọ́n. Bákan náà, bí wọ́n ṣe ṣètò igbe wọn yìí ló jẹ́ kí wọ́n lè máa dánu dúró nígbà tó bá yẹ.

 Nígbà tí àwọn tó ń wádìí nípa bí wọ́n ṣe ń gbé ìsọfúnni sí afẹ́fẹ́ rí bí àwọn ọ̀pọ̀lọ́ yìí ṣe máa ń gba ohùn fún ra wọn láì sí ìkọlùkọgbà, èyí wú wọn lórí, àwọn náà sì ṣètò bí a ṣe lè fi ìsọfúnni tó pọ̀ ránṣẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì lọ́nà tí ò lọ́jú pọ̀ kí wọ́n má sì kọ lu ra wọn. Nítorí náà, ohun tí wọ́n ṣe yìí jẹ́ kí Íńtánẹ́ẹ̀tì máa lọ geerege kò sì lo agbára tó pọ̀.

 Kí lèrò ẹ? Ṣé bí àwọn ọ̀pọ̀lọ́ Japanese Tree ṣe máa ń dánu dúró fúnra wọn kàn ṣàdédé wà ni? Àbí ẹnì kan ló ṣe iṣẹ́ àrà yìí?