Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Omi Tó Ń Yọ̀ Tó Wà Lára Ẹja Hagfish

Omi Tó Ń Yọ̀ Tó Wà Lára Ẹja Hagfish

 Ọjọ́ pẹ́ táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń ṣe kàyéfì nípa omi tó ń yọ̀ tàbí omi tó ki tó máa ń jáde lára ẹja hagfish. Kí nìdí tí wọ́n fi fẹ́ mọ̀ nípa bí omi ara rẹ̀ ṣe ń yọ̀? Ìdí ni pé omi tó ń yọ̀ tó ń jáde lára ẹja hagfish yìí jẹ́ ọ̀kan lára “ohun tó tíì fẹ́lẹ́ jù lọ tó sì máa ń fà bíi rọ́bà táa mọ̀.”

 Rò ó wò ná: Ẹja hagfish jẹ́ ẹja kan tó rí bí ejò tó sì máa ń gbé nísàlẹ̀ òkun. Tí ẹja hagfish bá kíyè sí i pé ohun kan fẹ́ pa òun jẹ, ó máa ń sun omi tó ki jáde látara ẹ̀. Èròjà purotéènì tó ki àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún fọ́nrán gígùn tó láwọn èròjà purotéènì míì wà nínú omi tó sun jáde yìí. Àwọn purotéènì náà á wá pa pọ̀, á wá mú kí omi tó wà lára ẹja hagfish di omi tó ki tó sì ń yọ̀. Omi tó ń yọ̀ yìí ló máa dí ẹ̀yà ara tí ẹranko tó fẹ́ pa á jẹ́ fi ń mí pa, ẹranko náà á sì tètè fi í sílẹ̀.

 Omi tó ń yọ̀ tó ń jáde láti ara ẹja hagfish yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an. Fọ́nrán purotéènì kọ̀ọ̀kan tó wà lára ẹ̀ fẹ̀ tó ìdá kan nínú ọgọ́rùn-ún irun èèyàn, ó sì fi ìlọ́po mẹ́wàá nípọn ju láílọ́ọ̀nù lọ. Tí ẹja yìí bá tú omi tó ń yọ́ yìí sínú òkun, àpòpọ̀ omi kíki àti fọ́nrán náà máa ń rí bí asẹ́ onígun mẹ́ta. Asẹ́ yìí lè gba omi tó fi ìlọ́po ẹgbẹ̀rún-ùn mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26,000) wúwo ju ara rẹ̀ lọ. Kódà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kìkì omi ló wà nínú omi tó ń yọ̀ náà!

 Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò tíì lè ṣe omi tó ń yọ̀ bíi èyí tó ń jáde lára ẹja hagfish. Olùṣèwádìí kan sọ pé “Ohun àdáyébá yìí díjú gan-an.” Síbẹ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fẹ́ lo òye ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tí wọ́n pè ní genetics láti mú fọ́nrán purotéènì míì jáde. Àfojúsùn wọn ni pé, kí wọ́n ṣe ohun èlò kan tí kò wúwo, tí kò lè tètè ya, tó ń ràn bíi rọ́bà, tí kò sì ní ba àyíká jẹ́. Wọ́n lè fi fọ́nrán purotéènì ṣe àwọn ohun èlò tí kò lè tètè bà jẹ́ tí wọ́n lè fi ṣe aṣọ, tí wọ́n sì lè fi ṣe àwọn ohun èlò tó máa wúlò fáwọn dókítà àtàwọn oníṣẹ́ abẹ. Ká sòótọ́, onírúurú nǹkan ni wọ́n á lè fi omi yìí ṣe.

 Kí lèrò rẹ? Ṣé omi ara ẹja hagfish tó jẹ́ ohun àrà yìí kàn ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀ ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?