Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Èèpo Ọsàn Pomelo Tó Rára Gba Nǹkan Sí

Èèpo Ọsàn Pomelo Tó Rára Gba Nǹkan Sí

 Ọsàn tí wọ́n ń pè ní Pomelo tóbi, ó sì dùn gan-an. Ohun kan tó yani lẹ́nu ni pé bí èso ẹ̀ bá tiẹ̀ já bọ́ láti orí igi tó ga ju mítà mẹ́wàá lọ, kò sí nǹkan tó máa ṣe ọsàn náà! Kí ló mú kí èso yìí rárá gba nǹkan sí?

 Rò ó wò ná: Àwọn tó ń ṣèwádìí ti rí i pé fùkùfùkù funfun tó wà nínú èèpo ọsàn pomelo ní àwọn sẹ́ẹ̀lì tó dà bíi kànrìnkàn tàbí tìmùtìmù tó ní àlàfo nínú. Àwọn àlàfo tó wà láàárín àwọn sẹ́ẹ̀lì náà máa ń fẹ̀ sí i bó ṣe ń wọnú ọsàn náà, atẹ́gùn tàbí omi ló sì máa ń wà láàárín àwọn àlàfo náà. Tí èso náà bá wá já bọ́, omi inú ẹ̀ á ṣiṣẹ́ bíi tìmùtìmù. Èèpo ọsàn náà á kóra jọ, á sì le. Ìyẹn gan-an ni kò ní jẹ́ kó fọ́ tàbí kó bà jẹ́.

 Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fẹ́ ṣe tìmùtìmù onírin tó rára gba nǹkan sí bíi ti èèpo ọsàn pomelo. Wọ́n gbà pé irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ á wúlò láti ṣe akoto táwọn oníkẹ̀kẹ́ tàbí àwọn tó ń gun ọ̀kadà máa ń dé. Wọ́n ń ronú àtifi ṣe ohun èlò tó lè mú kí mọ́tò túbọ̀ lágbára tó bá fara gbá nǹkan àti ààbò fún àwọn tó ń lọ sí gbalasa òfúrufú.

 Kí lèrò rẹ? Ṣé èèpo ọsàn pomelo tó rára gba nǹkan sí ṣàdédé wà ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?