Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Bí Àdán Ṣe Ń Fi Ìró Mọ Ohun Tó Wà Láyìíká Rẹ̀

Bí Àdán Ṣe Ń Fi Ìró Mọ Ohun Tó Wà Láyìíká Rẹ̀

 Àwọn àdán lè ríran, àmọ́ wọn ò lè ríran nínú òkùnkùn, torí náà èyí tó pọ̀ jù lára wọn ló máa ń fi ìró mọ bí nǹkan ṣe jìnnà sí wọn tó. Bí àpẹẹrẹ, àwọn àdán kan lè mọ̀ bóyá ẹ̀fọn tàbí ọlọ́bọ̀n-ùn-bọn-ùn ló wà láyìíká wọn, tí wọ́n bá kíyè sí bí kòkòrò náà ṣe ń ju ìyẹ́ rẹ̀.

 Rò ó wò ná: Ọ̀pọ̀ àwọn àdán máa ń mú ìró jáde láti ẹnu tàbí imú wọn. Wọ́n á wá fi etí wọn tó tóbi gbọ́ ìró náà lẹ́yìn tó ba ohun kan tó wà láyìíká wọn tó sì tún ta padà. Ìró tó ta padà yẹn máa ń jẹ́ kó lè fọkàn yàwòrán ohun tó wà láyìíká rẹ̀. Èyí máa ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àdán láti mọ ibi tí nǹkan wà, bí nǹkan náà ṣe jìnnà sí i tó, kó sì tún mọ̀ bóyá ṣe ni ibì kan lọ sókè tàbí lọ sílẹ̀, láìka ti pé àwọn àdán tó wà nítòsí ń mú ìró tiwọn náà jáde.

 Àdán gbọ́dọ̀ mọ ìró tó gbọ́ dáadáa, kí ohun tó rò pé ó wà níbi tí ìró náà ti ta padà sì dá a lójú, torí tó bá lọ ṣàṣìṣe pẹ́rẹ́, ó lè tàsé ohun tó fẹ́ jẹ. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan sọ pé kò sí bí àdán ò ṣe ní máa tàsé ohun tó fẹ́ jẹ tó bá wà nínú òkùnkùn. Àmọ́, ìwádìí ti jẹ́ kí wọ́n rí i pé àdán kì í tàsé ohun tó bá fẹ́ jẹ torí ó máa ń rọrùn fún un láti mọ bí nǹkan ṣe jìnnà sí i tó láìṣàṣìṣe rárá.

 Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣe igi kan tó máa ń jẹ́ káwọn afọ́jú mọ ohun tó wà láyìíká wọn, irú bí ohun tó wà lójú ọ̀nà àtèyí tó lè gbá wọn lórí bí ẹ̀ka igi. Méjì lára àwọn tó ṣe igi náà, ìyẹn Brian Hoyle àti Dean Waters sọ pé: “Ọ̀kan pàtàkì lára ohun tó mú ká lè ṣe igi náà ni bá a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí àwọn àdán ṣe máa ń fi ìró mọ ohun tó wà láyìíká wọn.”

 Kí lèrò ẹ? Ṣé o rò pé ṣe ni àdán ṣàdédé ń fi ìró mọ ohun tó wà láyìíká ẹ̀? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?