Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Bí Ajá Ṣe Ń Gbóòórùn

Bí Ajá Ṣe Ń Gbóòórùn

 Àwọn tó ń ṣèwádìí sọ pé ajá máa ń gbóòórùn gan-an, kódà wọ́n lè fi òórùn mọ ọjọ́ orí àwọn ajá míì, bóyá akọ ni wọ́n àbí abo, wọ́n sì lè fi mọ bí nǹkan ṣe rí lára àwọn ajá míì. Kódà, a lè dá àwọn ajá lẹ́kọ̀ọ́ lórí bí wọ́n á ṣe máa fi òórùn ṣàwárí àwọn nǹkan tí wọ́n fi ń ṣe bọ́ǹbù àtàwọn oògùn olóró tí ìjọba fòfin dè. Bó ṣe jẹ́ pé ojú làwa èèyàn fi sábà máa ń mọ ohun tó ń lọ láyìíká wa, imú làwọn ajá fi máa ń mọ̀ ọ́n ní tiwọn. Ká kúkú sọ pé imú ló ń ṣọnà fún wọn.

 Rò ó wò ná: Àwọn ajá máa ń gbóòórùn jù wá lọ fíìfíì. Àjọ National Institute of Standards and Technology lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé, ajá “lè gbóòórùn nǹkan tí kò ju bíńtín lọ, bí kò tiẹ̀ tó orí abẹ́rẹ́ pàápàá. Ṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n bá bu ṣúgà tó kéré tó ìlàrin ṣíbí ìjẹun sínú alagbalúgbú omi tó tó mílíọ̀nù kan lítà, téèyàn wá tọ́ ọ wò, tó sì mọ̀ pé ṣúgà wà nínú omi náà.”

 Kí ló mú kí ajá lè gbóòórùn jù wá lọ fíìfíì?

  •   Imú ajá máa ń tutù, ìyẹn máa ń jẹ́ kó rọrùn fún un láti gbóòórùn àwọn nǹkan kín-kìn-kín.

  •   Ihò méjì ni imú ajá ní​—ó ń fi ọ̀kan mí, ó sì ń fi ìkejì gbóòórùn. Tí ajá bá fa òórùn kan símú, ṣe ni atẹ́gùn máa ń gbé òórùn náà lọ sí apá ibi tó fi máa ń mọ òórùn nǹkan.

  •   Ibi tí ajá fi ń gbóòórùn nínú imú àti agbárí rẹ̀ fi, ó kéré tán, ìlọ́po mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) ju ti èèyàn lọ.

  •   Àwọn nǹkan tí ajá fi ń mọ òórùn fi ìlọ́po àádọ́ta (50) ju ti àwa èèyàn lọ.

 Gbogbo nǹkan yìí ló máa ń jẹ́ kí ajá lè fìyàtọ̀ sáàárín àwọn nǹkan tó para pọ̀ di òórùn tó ki. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan tó ń ṣèwádìí sọ pé, tẹ́nì kan bá ń se ọbẹ̀, àwa èèyàn lè gbóòórùn pé ọbẹ̀ ń ta sánsán. Àmọ́ ajá lè fi òórùn mọ èròjà kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ọbẹ̀ náà.

 Àwọn tó ń ṣèwádìí lórí àrùn jẹjẹrẹ ní iléeṣẹ́ Pine Street Foundation sọ pé iṣẹ́ tí ọpọlọ ajá àti imú rẹ̀ ń ṣe pa pọ̀ “wà lára ohun tó díjú jù lọ láyé yìí láàárín àwọn ohun tá a fi ń dá òórùn nǹkan mọ̀.” Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń ṣe àwọn ẹ̀rọ kan lọ́wọ́, tó ń ṣiṣẹ́ bí imú ajá, kí wọ́n lè máa fi ṣàwárí àwọn nǹkan tí wọ́n fi ń ṣe bọ́ǹbù àtàwọn ẹrù fàyàwọ́, kódà àwọn èrọ yìí máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ téèyàn bá ní àrùn, irú bí àrùn jẹjẹrẹ.

 Kí lèrò ẹ? Ṣé agbára tí ajá fi ń gbóòórùn kàn ṣàdédé wà ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?