Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Ahọ́n Ológbò

Ahọ́n Ológbò

 Ológbò táwọn èèyàn ń sìn nílé máa ń fẹ́ wà ní mímọ́ tónítóní. Nǹkan bí ìdá mẹ́rin àsìkò tí kò fi sùn ló máa ń fi tọ́jú ara ẹ̀. Ohun tó sì mú kíyẹn ṣeé ṣe ni bí ahọ́n ẹ̀ ṣe ní ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó máa ń jẹ́ kó lè nu irun ara ẹ̀.

 Rò ó wò ná: Ohun kan tí wọ́n ń pè ní papillae ló máa ń wà lórí ahọ́n, èyí tó sì wà lórí ahọ́n ológbò tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó dín mẹ́wàá (290). Ẹ̀yìn ni gbogbo ẹ̀ kọjú sí, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ nípọn tó èékánná ọwọ́ èèyàn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀ ló ní ohun tó dà bíi fóòmù tó máa ń fa itọ́ sára nígbà tí ológbò bá dá ahọ́n padà sẹ́nu. Torí náà, tí ológbò bá ń lá irun ara ẹ̀, àwọn papillae tó wà lórí ahọ́n ẹ̀ máa dé ìsàlẹ̀ irun níbi tí awọ wà, lẹ́yìn ìyẹn á wá tu itọ́ sórí awọ tó wà nísàlẹ̀ irun náà.

Fọ́tò papillae tí wọ́n mú kó tóbi

 Itọ́ tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá mẹ́ta agolo mílíìkì (nǹkan bíi 48 ml) ni ológbò máa ń fi ahọ́n fà sórí awọ ara ẹ̀ lójúmọ́. Itọ́ yìí sì ní àwọn èròjà tó máa ń pa kòkòrò. Yàtọ̀ síyẹn, bí itọ́ náà ṣe ń gbẹ ń ṣe ológbò láǹfààní gan-an. Ó wà lára ohun tó máa ń mú kí ara ẹ̀ tutù torí pé kì í fi bẹ́ẹ̀ làágùn.

 Tí ológbò bá ń lá irun ara ẹ̀, tí ahọ́n ẹ̀ wá kan irun tó lọ́ pa pọ̀, ṣe ni papillae tó kan irun náà máa gùn sí i kó lè wọnú irun tó lọ́ pa pọ̀ náà dáadáa, ìyẹn á sì jẹ́ kó lè tú irun náà. Ológbò tún máa ń fi ahọ́n yún ara ẹ̀, àwọn papillae tó wà lórí ahọ́n náà ló sì máa ń jẹ́ kíyẹn ṣeé ṣe. Àwọn tó ń ṣèwádìí ti ṣàyẹ̀wò ahọ́n ológbò kí wọ́n lè ṣe ìyarun tó dáa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ìyẹn ti mú kí wọ́n ṣe ohun tó lè ya irun tó lọ́ pa pọ̀ àtèyí tó lè ya irun láì sí pé èèyàn tẹ ọwọ́ mọ́ ọn, wọ́n tún ṣe é lọ́nà táá fi rọrùn láti nu ẹnu ẹ̀ lẹ́yìn téèyàn bá lò ó tán. Àwọn tó ń ṣèwádìí gbà pé tí wọ́n bá ṣàyẹ̀wò ahọ́n ológbò dáadáa, ìyẹn lè mú kó ṣeé ṣe fáwọn láti mọ ọ̀nà tó dáa jù lọ láti nu ojú ibi tí irun bá wà àti ibi tó nírun tó rán pọ̀. Bákan náà, wọ́n gbà pé ìyẹn lè jẹ́ kí wọ́n mọ ọ̀nà tó dáa jù lọ láti fi ìpara tàbí oògùn síbi tí irun bá wà.

 Kí lèrò ẹ? Ṣé ahọ́n ológbò kàn ṣàdédé wà ni? Àbí ẹnì kan ló ṣe iṣẹ́ àrà náà?