ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Dáàbò Bo Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Ohun Tó Ń Mú Ọkàn Fà sí Ìṣekúṣe

Dáàbò Bo Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Ohun Tó Ń Mú Ọkàn Fà sí Ìṣekúṣe

 “Ká sòótọ́, a mọ̀ pé àwòrán ìṣekúṣe burú jáì, àmọ́ a ò rò ó rí pé ọmọbìnrin wa lè wò ó.”​—Nicole.

Nínú àpilẹ̀kọ yìí

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀

 Àwọn ọmọ lè bẹ̀rẹ̀ sí í wo ohun tó ń mú kí ọkàn fà sí ìṣekúṣe láti kékeré. Ìwádìí fi hàn pé láti bí ọmọ ọdún mọ́kànlá (11) ni àwọn ọmọdé ti ń wo àwòrán ìṣekúṣe.

 Àwọn ọmọdé lè rí àwòrán ìṣekúṣe láìjẹ́ pé wọ́n wá a lórí ìkànnì. Bí àpẹẹrẹ, àwòrán ìṣekúṣe lè yọ sójú ẹ̀rọ wọn nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìwádìí tàbí nígbà tí wọ́n bá ń lo ìkànnì àjọlò. Nígbà míì tí wọ́n bá ń gbá géèmù orí Íńtánẹ́ẹ̀tì àwọn àwòrán tàbí fídíò tí wọ́n fi ń polówó ìṣekúṣe lè yọ sórí fóònù wọn. Onírúurú ọ̀nà la lè gbà rí ohun tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe, àmọ́ èyí tó wọ́pọ̀ jù ni àwòrán àti fídíò. Bákan náà, ó rọrùn gan-an láti ka àwọn ìtàn tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí ká tẹ́tí sí i.

 Ó yẹ káwọn òbí tún mọ̀ pé àwọn èèyàn kan lè fi àwòrán ìṣekúṣe ránṣẹ́ sí orí fóònù ọmọ wọn. Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe fún àwọn ọ̀dọ́ tó jú ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900), nǹkan bí ọmọbìnrin mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá àti ọmọkùnrin márùn-ún nínú mẹ́wàá làwọn ọmọ kíláàsì wọn ń fi àwòrán oníhòhò ránṣẹ́ sí látìgbàdégbà.

 Ọ̀pọ̀ àwòrán ìṣekúṣe ló ní ìwà ipá. Àwọn àwòrán àti fídíò ìṣekúṣe tó wọ́pọ̀ gan-an lónìí ni wọ́n ti ń hùwà ipá sáwọn obìnrín nínú ẹ̀.

 Àwòrán ìṣekúṣe máa ń pa àwọn ọmọdé lára. Ìwádìí fi hàn pé ó ṣeé ṣe káwọn ọmọ tó máa ń wo àwọn ohun tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe ní àwọn ìṣòro yìí:

  •   wọn kì í ṣe dáadáa nílé ìwé

  •   wọ́n máa ń ṣàníyàn, ọkàn wọn kì í balẹ̀, wọ́n sì máa ń wo ara wọn bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan

  •   wọn kì í rí ohun tó burú nínú kí wọ́n fi agídí bá ẹni kan lò pọ̀

 Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Ohun tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe máa ń ṣe ìpalára tó pọ̀ fáwọn ọmọdé, àwọn òbí ló sì wà nípò tó dáa jù láti ràn wọ́n lọ́wọ́.

 Ìlànà Bíbélì: “Rí i pé o fi àwọn ọ̀rọ̀ yìí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sọ́kàn, kí o máa fi kọ́ àwọn ọmọ rẹ léraléra, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ, nígbà tí o bá ń rìn lójú ọ̀nà, nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.”​—Diutarónómì 6:6, 7.

 Bó o ṣe lè dáàbò bo ọmọ rẹ lọ́wọ́ ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe

 Wà lójúfò. Ronú nípa ibi tí ọmọ rẹ ti lè rí àwọn ohun tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe àti ìgbà tó ṣeé ṣe kó wò ó. Bí àpẹẹrẹ, ṣé wọ́n máa ń fún wọn láǹfààní láti lo Íńtánẹ́ẹ̀tì lákòókò ìsinmi nílé ìwé?

Onírúurú ibi ni ọmọ rẹ ti lè rí àwọn ohun tó ń mọ́kàn fà sí ìṣekúṣe

 Mọ àpadé-àludé bí fóònù ọmọ rẹ a ṣe ń ṣiṣẹ́, kó o sì mọ àwọn ìkànnì tó máa ń lọ déédéé àtàwọn géèmù tó máa ń gbá. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìkànnì àjọlò kan máa ń ní ohun tó lè mú kí ọ̀rọ̀, àwòràn àti fídíò tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí ẹni kan “pòórá” lẹ́yìn àkókó díẹ̀ tí wọ́n bá fi ránṣẹ́. Bí àwọn géèmù orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ṣe ń pọ̀ sí i, àwọn kan máa ń jẹ́ kí àwọn tó ń gbá géèmù náà wo àwọn ohun tó mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe, kí wọ́n sì lọ́wọ́ sí i látórí ìkànnì.

 “Ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí mi rí jẹ́ kí ń mọ̀ pé tí ọmọ rẹ bá ní fóònù ìgbàlódé, ó yẹ kíwọ́ fúnra rẹ mọ bí wọ́n ṣe ń lò ó, kó o sì mọ ohun tó o lè ṣe sí fóònù rẹ̀ tó lè dénà wíwó ohun tó lè mú ki ọkàn rẹ̀ fà sí ìṣekúṣe. Bákan náà, ó yẹ kó o máa wo bó ṣe ń lo fóònù náà lóòrèkóòrè.”​—David.

 Ìlànà Bíbélì: “Ọkàn ẹni tó ní òye ń gba ìmọ̀.”​—Òwe 18:15.

 Sapá láti dáàbò bo ọmọ rẹ. Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kí ọmọ rẹ má bàa kó sínú wàhálà. Bí àpẹẹrẹ, o lè dènà ibi tí ọmọ rẹ ti lè rí àwòrán ìṣekúṣe bóyá lórí fóònù rẹ̀ tàbí lorí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé míì tó wà nínú ilé yín. Bákan náà, rí i pé o mọ àwọn ọ̀rọ̀ ìwọlé sórí fóònù ọmọ rẹ.

 “Mo rí i pé ó bọ́gbọ́n mu kí n mọ ọ̀rọ̀ ìwọlé sórí fóònù ọmọ mi, mo sì fi ààlà sí ibi tó lè dé lórí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tó wà nínú ilé wa títí kan tẹlifíṣọ̀n.”​—Maurizio.

 “Tí àwọn ọmọkùnrin mi bá ń wo fíìmù nínú yàrá wọn, mi ò kì í gbà kí wọ́n ti ilẹ̀kùn. Tí wọ́n bá sì fẹ́ lọ sùn mi ò kì í jẹ́ kí wọ́n mú fóònù wọlè.”​—Gianluca.

 Ìlànà Bíbélì: “Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fara pa mọ́.”​—Òwe 22:3.

 Múra ọmọ rẹ sílẹ̀. Ìyá kan tó ń jẹ́ Flavia sọ pé: “Àwọn òbí kan kì í bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó lè mú kí ọkàn wọn fà sí ìṣekúṣe, torí wọ́n gbà pé àwọn ọmọ wọn ò lè ní irú ìṣòro bẹ́ẹ̀.” Èrò àwọ̀n òbí míì sì ni pé, táwọn bá sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ pẹ́nrẹ́n, ìyẹn lè jẹ́ kó máa wu ọmọ wọn láti wò ó. Àmọ́, Irú èrò yìí ò tọ̀nà rárá. Àwọn òbí tó gbọ́n máa ń kọ́ ọmọ wọn nípa ewu tó wà nínú wíwo ohun tó lè mú kí ọkàn fà sí ìṣekúṣe, kó tó di pé ó bá irú nǹkan bẹ́ẹ̀ pàdé lórí ìkànnì àjọlò. Ohun tó o sì lè ṣe rèé:

 Jẹ́ kí ọmọ rẹ tó ṣì kéré mọ ohun tó lè ṣe tó bá ṣèèṣì rí ohun tó lè mú kọ́kàn fà sí ìṣekúṣe. Bí àpẹẹrẹ, á dáa kó gbé ojú rẹ̀ kúrò tàbí kó tiẹ̀ pa fóònù rẹ̀ tó bá rí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀. Sọ fún un pé kó má bẹ̀rù láti sọ ohunkóhun tó bá rí tàbí tó gbọ́. b

 “Ìgbà tọ́mọ wa ṣì kére la ti bá a sọ̀rọ̀ nípa èwù tó wà nínú wíwó àwòrán ìṣekúṣe. Nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mọ́kànlá (11ni àwòrán ìṣekúṣe tí wọ́n fi ń polówó ọjà ti ń yọ lórí fóònù rẹ̀ tó bá fi ń gbá géèmù. Wọ́n wá sọ pé kó fi àwòrán ìhòhò rẹ̀ ránṣẹ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe ìpolówó náà. Àmọ́, torí pé a ti jọ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ tẹ́lẹ̀, ojú ẹsẹ̀ ló wá sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún mi.”​—Maurizio.

 Ìlànà Bíbélì: “Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tó yẹ kó tọ̀; kódà tó bá dàgbà, kò ní kúrò nínú rẹ̀.”​—Òwe 22:6.

 Ran àwọn ọmọ rẹ tó ti ń dàgbà lọ́wọ́ kí wọ́n lè sá fún ohunkóhun tó lè mú kí ọkàn wọn fà sí ìṣekúṣe, ì báà jẹ́ ohun tí wọ́n ń wò, tí wọ́n ń gbọ́ tàbí tí wọ́n ń kà. Bí àpẹẹrẹ, o lè ní kí ọmọ rẹ kọ ohun tó máa ṣe sílẹ̀ tó bá ṣèèṣì rí ohun tó lè mú kọ́kàn rẹ̀ fà sí ìṣekúṣe lórí ìkànnì àti ìdí tó fí yẹ kó ṣe ohun náà. Kò sì tún kọ ohun tó máa jẹ́ àbájáde rẹ̀ tó bá dìídì wò ó. Lára ẹ̀ sì ní pé kò ní níyì lójú ara ẹ̀ mọ́, àwọn òbí ẹ̀ lè má fọkàn tán an, àti pe inú Ọlọ́run ò ní dùn sí i. c

 “Bí àwọn ọmọ rẹ ṣe ń dàgbà, ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa ronú lórí ohun tó máa jẹ́ àbájáde rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú tí wọ́n ò bá sá fún wíwo àwòrán ìṣekúṣe.”​—Lauretta.

 “Tí àwọn ọmọ wa bá mọ ewu tó wà nínú wíwo àwòrán ìṣekúṣe tí wọ́n sì tún mọ bí irú ìwà yìí ṣe máa ń rí lára Jèhófà, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n lè sá fún un.”​—David.

 Ìlànà Bíbélì: “Ọgbọ́n jẹ́ ààbò.”​—Oníwàásù 7:12.

 Ẹ jọ máa sọ̀rọ̀ déédéé. Òótọ́ kan ni pé àwọn ọmọ máa ń fẹ́ bá àwọn òbí wọn sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ títí kan ọ̀rọ̀ nípa ohun tó lè mú kó máa wù wọ́n láti ṣe ìṣekúṣe. Dame Rachel de Souza tó jẹ́ Kọmíṣọ́nnà lórí ọ̀rọ̀ àwọn Ọmọdé ní England sọ pé: “Ohun tá a ti rí ni pé, àwọn ọmọ máa ń fẹ́ bá àwọn òbí wọn sọ̀rọ̀ léraléra nípa ìbálòpọ nígbà tí wọ́n ṣì kéré. Báwọn ọmọ yìí ṣe ń dàgbà wọ́n máa ń fẹ́ káwọn òbí wọ́n bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ohunkóhun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbálòpọ bọ́jọ́ orí wọn ṣe tó.”

 “Nígbà tí mo ṣì kéré, àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì kan wà táwọn òbí mi ò bá mi sọ. Ó dùn mí pé àwọn òbí mi kì í bá mi sọ̀rọ̀ déédéé, tàbí kí n tiẹ̀ sọ bí nǹkan ṣe rí lára mi fún wọn. Àmọ́ ní báyìí tí mo ti di òbí, mo máa ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti bá àwọn ọmọ mi sọ̀rọ̀ déédéé nípa ìbálòpọ̀ lọ́nà tó máa tù wọ́n lára.”​—Flavia.

 Kí lo lè ṣe tí ọmọ rẹ bá ti ń wo àwòrán ìṣekúṣe?

 Fara balẹ̀. Ma gbaná jẹ́ tó o bá kíyè sí pé ọmọ rẹ ti lọ́wọ́ sí ohunkóhun to ń mú kí ọkàn rẹ̀ fà sí ìṣekúṣe. Fi sọ́kàn pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí lè má múnú òun náà dùn, ó lè bá a lójijì tàbí kó tiẹ̀ kábàámọ̀ rẹ̀. Torí náà ṣe lo kàn máa dá kún ìṣòro rẹ̀ tó o bá binú sódì. Ìyẹn sì lè mú kó má sọ fún ẹ mọ́ tó bá tún pa dà nírú ìṣòro yìí lọ́jọ́ iwájú.

 Ìlànà Bíbélì: “Ẹni tó ní ìmọ̀ máa ń ṣọ́ ọ̀rọ̀ tó ń sọ, ẹni tó sì ní òye kì í gbaná jẹ.”​—Òwe 17:27.

 Mọ ohun tó ṣẹlẹ̀. Dípò kó o kàn gbà pé o mọ ohun tó fà á tí ọmọ rẹ fi wo àwòrán ìṣekúṣe, ṣe ni kó o béèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ṣe ẹnì kan ló fi àwòràn náà ránṣẹ́ sí i tàbí ṣe ló fúnra rẹ̀ wá a? Ṣé ìgbà àkọ́kọ́ rèé tó máa wò ó àbí ó ti ń wò ó tẹ́lẹ̀? Ṣé kì í ṣe pé ṣe ló lọ wá ọ̀nà míì kó lè wá a jáde lẹ́yìn tó o ti fi ààlà síbí tó ti lè rí i lórí fóònù rẹ̀? Fí sọ́kàn pé ìdí tó o fẹ́ fi mọ àwọn nǹkan yìí ni kó o lè ràn án lọ́wọ́ kì í ṣe kó o lè wá ọ̀nà láti fìyà jẹ ẹ́.

 Ìlànà Bíbélì: “Èrò ọkàn èèyàn dà bí omi jíjìn, àmọ́ olóye ló ń fà á jáde.”​—Òwe 20:5.

 Gbé ìgbésẹ̀. Bi àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé ṣe ló kàn ṣèèṣì rí i, á jẹ́ pé o máa tún ní láti ṣiṣẹ́ lórí ibi tó lè dé lórí fóònù rẹ̀.

 Tó bá jẹ́ pé ṣe ló fúnra rẹ̀ wá a, bá a wí tìfẹ́tìfẹ́ kó o má sì fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Sapá láti kọ́ ọmọ rẹ kó lè sá fún ohunkóhun tó lè mú kó ṣe ìṣekúṣe. O lè fi àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí ràn án lọ́wọ́; Jóòbù 31:1, Sáàmù 97:10 àti Sáàmù 101:3. d Bákan náà, jẹ́ kó mọ̀ pé ẹ̀ẹ́ jọ máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ kó o lè mọ ibi tọ́rọ̀ náà dé àtohun míì tó o lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́.

 Ìlànà Bíbélì: “Ẹ̀yin bàbá, ẹ má ṣe máa mú àwọn ọmọ yín bínú, kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa tọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìmọ̀ràn Jèhófà.”​—Éfésù 6:4.

a Ìsọfúnni yìí wúlò fún tọkùnrin tobìnrin.

b Tó o bá fẹ́ mọ bó o ṣe lè bá àwọn ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ níbàámu pẹ̀lú ọjọ́ orí wọn, ka àpilẹ̀kọ náà “Báwo Ni Àwọn Òbí Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Ọmọ Wọn Nípa Ìbálòpọ̀?

c Tó o bá fẹ́ mọ àwọn ohun tí ọmọ rẹ tún lè kọ sínú iwé náà, ka Ìwé Àjákọ fún Àwọn Ọ̀dọ́ “Bí O Ṣe Lè Yẹra fún Wíwo Àwòrán Ìṣekúṣe.”

d Ẹ tún lè jọ ka àpilẹ̀kọ náà “Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Yẹra fún Wíwo Àwòrán Ìṣekúṣe?