Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Ọ̀run Àpáàdì Wà Lóòótọ́? Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ọ̀run Àpáàdì?

Ṣé Ọ̀run Àpáàdì Wà Lóòótọ́? Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ọ̀run Àpáàdì?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan tó ti pẹ́ lo ọ̀rọ̀ náà “ọ̀run àpáàdì” nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì kan. (Sáàmù 16:10; Ìṣe 2:27 a) Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ yìí ṣe máa fi hàn, ohun tí àwọn ìsìn fi ń kọ́ni ni pé, ọ̀run àpáàdì jẹ́ ibi tí a ti ń fi iná dá àwọn èèyàn burúkú lóró títí ayérayé. Àmọ́, ṣe ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nìyẹn?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí

 Ṣé ọ̀run àpáàdì jẹ́ ibi tí a ti ń dá àwọn èèyàn lóró lóòótọ́?

 Rárá o. Ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tá a tú sí “ọ̀run àpáàdì” nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tó ti pẹ́ (Hébérù, “Ṣìọ́ọ̀lù”; Gíríìkì, “Hédíìsì”) ní tààràtà ń tọ́ka sí “Isà òkú,” ìyẹn sàréè tí wọ́n ń sin àwọn èèyàn sí. Bíbélì fi hàn pé àwọn tó wà ní “Isà òkú” ò sí níbì kankan.

  •   Àwọn òkú ò mọ nǹkan kan, torí náà wọn ò lè jẹ̀rora. “Nítorí kò sí iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ìpinnu tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú isà òkú níbi tí ò ń lọ.” (Oníwàásù 9:10, Bibeli Mimọ) Àwọn èèyàn kì í jẹ̀rora ní ọ̀run àpáàdì. Àmọ́, ohun tí Bíbélì sọ ni pé: “Jẹ́ kí ojú kí ó ti ènìyàn búburú, jẹ́ kí wọ́n lọ pẹ̀lú ìdààmú sí isà òkú.”​—Sáàmù 31:17 Bibeli Mimọ; Sáàmù 115:17.

  •   Ọlọ́run sọ pé ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, kì í ṣe ìdálóró nínú iná ọ̀run àpáàdì. Ọlọ́run sọ fún Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́ pé tó bá rú òfin òun, ikú ló máa jẹ́ èrè rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Kò sọ ohunkóhun nípa ìdálóró ayérayé ní ọ̀run àpáàdì. Lẹ́yìn tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, Ọlọ́run sọ fún un pé: “Erùpẹ̀ ni ọ́, ìwọ yóò sì pa dà sí erùpẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Ìyẹn ni pé kò ní sí mọ́. Ọlọ́run ì bá ti sọ ọ́ ká ní lóòótọ́ ló fẹ́ kí Ádámù lọ sínú iná ọ̀run àpáàdì, kò sì tíì yí ìyà tó fi ń jẹ àwọn tí wọ́n bá rú òfin rẹ̀ pa dà. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, Ọlọ́run mí sí òǹkọ̀wé Bíbélì kan láti sọ pé: “Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀.” (Róòmù 6:23) Kò sí ìdí láti fìyà jẹ ẹni tó ti kú mọ́, torí “ẹni tó bá ti kú ni a ti dá sílẹ̀ pátápátá kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”​—Róòmù 6:7.

  •   Ìdálóró ayérayé jẹ́ ohun ìríra lójú Ọlọ́run. (Jeremáyà 32:35) Irú èrò bẹ́ẹ̀ ta ko ohun tí Bíbélì sọ, pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Ó fẹ́ ká máa jọ́sìn òun torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kì í ṣe torí ìbẹ̀rù ìdálóró ayérayé.​—Mátíù 22:36-38.

  •   Àwọn èèyàn rere náà lọ sọ́run àpáàdì. Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tó lo ọ̀rọ̀ náà “ọ̀run àpáàdì” fi hàn pé, àwọn olóòótọ́ èèyàn bíi Jékọ́bù àti Jóòbù náà lọ síbẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 37:35; Jóòbù 14:13) Kódà, Bíbélì sọ pé Jésù Kristi náà wà ní ọ̀run àpáàdì láàárín ìgbà tó kú sígbà tó jíǹde. (Ìṣe 2:31, 32) Ó ṣe kedere nígbà náà pé, bí a ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “ọ̀run àpáàdì” nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí fi hàn pé isà òkú ló ń tọ́ka sí. b

 Kí ni àkàwé Jésù nípa ọkùnrin ọlọ́rọ̀ àti Lásárù túmọ̀ sí?

 A lè rí àkàwé tí Jésù lò yìí nínú Lúùkù 16:19-31. Àkàwé jẹ́ àwọn àpèjúwe tó ń jẹ́ ká lóye òtítọ́ ká sì mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan. Torí náà, àkàwé ọkùnrin ọlọ́rọ̀ àti Lásárù kì í ṣe ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ti gidi. (Mátíù 13:34) Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa àkàwé náà, wo àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Ta Ni Ọkùnrin Ọlọ́rọ̀ Náà àti Lásárù?

 Ṣé àwọn èèyàn burúkú tó jìnnà sí Ọlọ́run ló ń lọ sí ọ̀run àpáàdì?

 Rárá o. Àwọn ìsín kan ń kọ́ni pe àwọn òkú mọ̀ bóyá àwọn ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Èyí sì ta ko ohun tí Bíbélì sọ pé àwọn òkú ò mọ nǹkan kan rárá.​—Sáàmù 146:3, 4; Oníwàásù 9:5.

 Ṣé ẹnikẹ́ni tiẹ̀ ti jade láti ọ̀run àpáàdì rí?

 Bẹ́ẹ̀ ni. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn mẹ́sàn-án tí wọ́n lọ sínú isà òkú (tí wọ́n túmọ̀ sí “ọ̀run àpáàdì” nínú àwọn Bíbélì kan) àmọ́ tí Ọlọ́run jí wọn dìde pa dà. c Ká sọ pé wọ́n mọ bí nǹkan ṣe rí nígbà tí wọ́n wà ní ọ̀run àpáàdì, wọn ì bá ti sọ bí nǹkan ṣe rí nígbà tí wọ́n jíǹde. Àmọ́, kò sí èyíkéyìí nínú wọn tó sọ̀rọ̀ nípa ìdálóró, tàbí tó sọ pé òun ní ìmọ̀lara kankan níbẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn òkú ò mọ nǹkan kan rárá bí Bíbélì ṣe fi kọ́ni, ṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n “sùn” oorun àsùnwọra.​—Jòhánù 11:11-14; 1 Kọ́ríńtì 15:3-6.

a Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì òde òní ni ò lo ọ̀rọ̀ náà “ọ̀run àpáàdì” nínú Ìṣe 2:27. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi “isà òkú,” (Bibeli Mimọ); “ibùgbé àwọn òkú,” (Yoruba Bible); “ipò-òkú” (The Passion Translation). Àwọn míì kàn tú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà lólówuuru sí “Hédíìsì.”​—Holman Christian Standard Bible, NET Bible, New American Standard Bible, English Standard Version.