Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Ẹfolúṣọ̀n Ni Ọlọ́run Lò Láti Dá Àwọn Nǹkan?

Ṣé Ẹfolúṣọ̀n Ni Ọlọ́run Lò Láti Dá Àwọn Nǹkan?

Ohun tí Bíbélì sọ

Rárá o. Bíbélì sọ lọ́nà tó ṣe kedere pé Ọlọ́run dá àwọn èèyàn, àwọn ẹranko àtàwọn ewéko ní “irú” tiwọn. a (Jẹ́nẹ́sísì 1:12, 21, 25, 27; Ìfihàn 4:11) Bíbélì sọ pé ọ̀dọ̀ Ádámù àti Éfà, ìyẹn àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ni gbogbo ìdílé ẹ̀dá èèyàn ti ṣẹ̀ wá. (Jẹ́nẹ́sísì 3:20; 4:1) Bíbélì ò kọ́ wa pé ẹfolúṣọ̀n ni Ọlọ́run lò láti dá onírúurú àwọn nǹkan. Irú èrò yìí ni wọ́n sábà máa ń pé ní theistic evolution. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, kò sí ibì kankan tí Bíbélì ti ta ko àwọn ìwádìí táwọn sáyẹ́ǹsì ṣe pé àwọn ìyàtọ̀ máa ń wà nínú onírúurú ìṣẹ̀dá. b

 Ṣé Ẹfolúṣọ̀n ni Ọlọ́run lò?

Ọ̀rọ̀ náà “theistic evolution” (ìyẹn ìgbàgbọ́ pé ẹfolúṣọ̀n ni Ọlọ́run lò láti dá onírúurú nǹkan) gbòòrò gan-an. Bí ìwé Encyclopædia Britannica ṣe sọ, ọ̀rọ̀ náà gbé èrò náà lárugẹ pé “ẹfolúṣọ̀n jẹ́ ọ̀nà kan tí Ọlọ́run ń lò láti darí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé.”

Ẹ̀kọ́ yìí tún lè ní àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí nínú:

  • Pé ọ̀dọ̀ ẹ̀dá alààyè kan náà ni gbogbo ẹ̀dá alààyè ti ṣẹ̀ wá.

  • Pé oríṣi ìwàláàyè kan lè yíra pa dà pátápátá sí irú ìwàláàyè míì, èrò yìí ni wọ́n sábà máa ń pè ní macroevolution. (ìyẹn ìyípadà ẹfolúṣọ̀n lọ́nà tó gbòòrò gan-an irú bí kí ẹranko di èèyàn).

  • Pé Ọlọ́run gan-an ló mú kí àwọn ìyípadà yìí wáyé.

 Ṣé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n bá Bíbélì mu?

Theistic evolution (ìyẹn ìgbàgbọ́ pé ẹfolúṣọ̀n ni Ọlọ́run lò láti dá onírúurú nǹkan) ń jẹ́ kéèyàn máa rò pé àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ìṣẹ̀dá tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì kò fi bẹ́ẹ̀ péye. Àmọ́, Jésù tọ́ka sí àkọsílẹ̀ ìwé Jẹ́nẹ́sísì pé òótọ́ ni ìtàn náà. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 27; 2:18-24; Mátíù 19:4-6) Bíbélì sọ pé ṣáájú kí Jésù tó wá sáyé, ó ti gbé pẹ̀lú Ọlọ́run, ó sì ran Ọlọ́run lọ́wọ́ láti mú kí “ohun gbogbo” wà. (Jòhánù 1:3) Torí náà, èrò náà pé ẹfolúṣọ̀n ni Ọlọ́run lò láti ṣẹ̀dá àwọn nǹkan kò bá Bíbélì mu.

 Kí la lè sọ nípa agbára tí àwọn ewéko àti ẹranko ní láti mú ara wọn bá àyíká mu?

Bíbélì kò ṣàlàyé bí ìyípadà tó máa bá irú oríṣi ìwàláàyè kan ṣe máa pọ̀ tó. Bẹ́ẹ̀ ni kò sì ta ko òtítọ́ náà pé onírúurú ewéko àti ẹranko tí Ọlọ́run dá lè bí àwọn ọmọ tó yàtọ̀ síra àti pé wọ́n lè mú ara wọ́n bá àyíká tí wọ́n bá bá ara wọn mu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ń wo irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ bí ẹfolúṣọ̀n, ṣùgbọ́n kò sí irú ìwàláàyè tuntun kan táá mú jáde.

a Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà “irú,” tí ìtumọ̀ rẹ̀ gbòòrò ju “oríṣi” bí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣe máa ń lò ó. Lọ́pọ̀ ìgbà, táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì bá sọ pé oríṣi ohun alààyè tuntun kan ti hú yọ, ohun tó máa ń jẹ́ ni pé irú míì lára ìṣẹ̀dá tó ti wà tẹ́lẹ̀ ni wọ́n ń pè ní ohun tuntun. Ìwé Jẹ̀nẹ́sísì sì lo ọ̀rọ̀ náà “irú” láti fi èyí hàn.

b Èrò yìí ni wọ́n máa sábà máa ń pè ní microevolution (ìyẹn ìyípadà ẹfolúṣọ̀n lọ́nà tó kéré gan-an.)