Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba gidi tí Jèhófà Ọlọ́run gbé kalẹ̀. Bíbélì tún pe “Ìjọba Ọlọ́run” ní “Ìjọba ọ̀run” torí pé láti ọ̀run lá ti máa ṣàkóso. (Máàkù 1:14, 15; Mátíù 4:17, Bíbélì Mímọ́) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ní àwọn ọ̀nà kan a lè fi wé ìjọba àwọn èèyàn, ó dára jù wọ́n lọ ní gbogbo ọ̀nà.

  •   Àwọn alákòóso. Ọlọ́run ti yan Jésù Kristi láti jẹ́ Ọba Ìjọba náà, ó sì fún un ní ọlá àṣẹ́ tó ju èyí ti ìkankan lára àwọn alákòóso tó jẹ́ èèyàn lè ní lọ. (Mátíù 28:18) Kìkì ohun rere ni Jésù máa ń lo agbára rẹ̀ yìí fún, a mọ èyí torí pé ó ti fi hàn pé òun jẹ́ Aṣáájú tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé tó sì lójú àánú. (Mátíù 4:23; Máàkù 1:40, 41; 6:31-34; Lúùkù 7:11-17) Ọlọ́run darí Jésù láti yan àwọn èèyàn láti gbogbo orílẹ̀-èdè kí wọ́n lè jọ “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí” láti ọ̀run.—Ìṣípayá 5:9, 10.

  •   Àkókò. Ìjọba náà kò dà bíi ti ìjọba èèyàn tó máa n fìgbà kan wà, tí kò sì ní sí mọ́. Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ “èyí tí a kì yóò run láé.”—Dáníẹ́lì 2:44.

  •   Ọmọ abẹ́ ìjọba. Ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ lè di ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, láìka ibi tí wọ́n ti bí i, tàbí ẹni tó bí i sí.—Ìṣe 10:34, 35.

  •   Àwọn òfin. Kì í ṣe pé àwọn òfin (tàbí àwọn àṣẹ) Ìjọba Ọlọ́run ka ìwà burúkú léèwọ̀ nìkan ni, ó tún ń jẹ́ kí àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba náà máa hùwá rere. Bí àpẹ́ẹrẹ, Bíbélì sọ pé: “‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní. Èkejì, tí ó dà bí rẹ̀, nìyí, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’” (Mátíù 22:37-39) Ìfẹ́ tí àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba náà ní fún Ọlọ́run àti àwọn èèyàn máa ń mú kí wọ́n fẹ́ ṣe ohun tó dára fún àwọn míì.

  •   Ẹ̀kọ́. Àwọn ìlànà tó ga ju tí èèyàn lọ ni Ìjọba Ọlọ́run gbé kalẹ̀ fún àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀, síbẹ̀ ó ń kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà náà.—Aísáyà 48:17, 18.

  •   Ohun tó fẹ́ ṣe. Àwọn tó ń ṣàkóso nínú Ìjọba Ọlọ́run kò ní máa rẹ́ àwọn èèyàn jẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n á ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, títí kan mímú ìlérí tí Ọlọ́run ṣe ṣẹ pé àwọn tó fẹ́ràn òun máa gbé inú párádísè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.—Aísáyà 35:1, 5, 6; Mátíù 6:10; Ìṣípayá 21:1-4.