Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Ìwé Àwọn Aláwọ̀ Funfun Ni Bíbélì?

Ohun tí Bíbélì sọ

Kì í ṣe àwọn ọmọ ilẹ̀ Yúróòpù ló kọ Bíbélì. Ilẹ̀ Éṣíà ni gbogbo àwọn tí Ọlọ́run lò láti kọ Bíbélì ti wá. Bíbélì kò gbé ẹ̀yà kan ga ju òmíràn lọ. Kódà, Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.—Ìṣe 10:34, 35.