Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kọrin sí Jèhófà—Àwọn Orin Tuntun

 Orin 152

Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbẹ́kẹ̀lé Wa

Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbẹ́kẹ̀lé Wa

Wà á jáde:

(Òwe 14:26)

 1. Jèhófà, o fún wa nírètí

  èyí tí à ńṣìkẹ́.

  Ìrètí yìí ńmúnú wa dùn

  a fẹ́ sọ fáyé gbọ́.

  Nígbà míì, ìṣòro ayé yìí

  máa ńmú kí ẹ̀rù bà wá,

  Ìrètí tó ńmú ọkàn yọ̀

  kò wá lágbára mọ́.

  (ÈGBÈ)

  Agbára, Ìrètí

  Ìgbẹ́kẹ̀lé wa.

  O máa ńbá wa gbé ‘ṣòro wa.

  À ńwàásù, à ńkọ́ni,

  ọkàn wa balẹ̀

  torí ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé.

 2. Jọ̀ọ́ Jèhófà, jẹ́ ká máa rántí

  pé o wà lẹ́yìn wa,

  ’Gbà gbogbo lò ńtù wá nínú

  tí ìṣòro bá dé.

  Àwọn ìrònú tó ńmókun wá

  lè mú k’írètí sọjí,

  Wọ́n ńjẹ́ ká lè fi ìgboyà

  kéde orúkọ rẹ.

  (Ègbè)

  Agbára, Ìrètí

  Ìgbẹ́kẹ̀lé wa.

  O máa ńbá wa gbé ‘ṣòro wa.

  À ńwàásù, à ńkọ́ni,

  ọkàn wa balẹ̀

  torí ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé.