Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kọrin sí Jèhófà—Àwọn Orin Tuntun

 Orin 150

Wá Wọn Lọ

Wá Wọn Lọ

Wà á jáde:

(Mátíù 9:37, 38)

 1. Jèhófà mọ ohun tó máa

  Jẹ́ ká láyọ̀, káyé yẹ wá.

  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní wà

  Ká fayé wa sin Ọlọ́run.

  (ÈGBÈ)

  Wá wọn lọ, sapá gan-an,

  ṣiṣẹ́ Ọlọ́run.

  Sìn níbi tí àìní pọ̀ sí gan-an,

  fìfẹ́ wá wọn lọ.

 2. Kò síbi tí iṣẹ́ kò sí.

  Níbi àìní, lọ ṣèrànwọ́.

  Tá  a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a nífẹ̀ẹ́ wọn.

  Ká lọ síbẹ̀, ká lọ wàásù.

  (ÈGBÈ)

  Wá wọn lọ, sapá gan-an,

  ṣiṣẹ́ Ọlọ́run.

  Sìn níbi tí àìní pọ̀ sí gan-an,

  fìfẹ́ wá wọn lọ.

 3. Tó  ò bá lè lọ, níbi tó  o wà,

  Múra sílẹ̀, máa sunwọ̀n sí  i.

  Sapá láti kọ́ èdè mí ì

  Kó  o lè wàásù f’ọ́pọ̀ èèyàn.

  (ÈGBÈ)

  Wá wọn lọ, sapá gan-an,

  ṣiṣẹ́ Ọlọ́run.

  Sìn níbi tí àìní pọ̀ sí gan-an,

  fìfẹ́ wá wọn lọ.