Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kọrin sí Jèhófà—Àwọn Orin Tuntun

 Orin 148

O Fún Wa Ní Ọmọ Rẹ Kan Ṣoṣo

O Fún Wa Ní Ọmọ Rẹ Kan Ṣoṣo

Wà á jáde:

(Jòhánù 15:13)

 1. Jèhófà, Baba wa,

  Nígbà tá  ò nírètí.

  O pèsè ’ràpadà

  Ká lè nírètí!

  A  ó fayé wa sìn ọ́,

  Gbogbo ohun tá  a jẹ́.

  A  ó wàásù fáráyé,

  Kí ìfẹ́ rẹ lè ṣẹ.

  (ÈGBÈ)

  O fún wa l’Ọ́mọ rẹ,

  A sì ń  kọrin yìn ọ́,

  A  ó máa yìn ọ́ títí láé,

  fún bó  o ṣe fún wa l’Ọ́mọ rẹ.

 2. Àánú rẹ, oore rẹ,

  Ló ń  jẹ́ ká sún mọ́ ọ.

  Oókọ rẹ, ìfẹ́ rẹ,

  Sí wa dùn mọ́ wa.

  Ẹ̀bùn tó dára jù

  Ni ọmọ rẹ ọ̀wọ́n.

  Ó kú ká lè níyè.

  Ìwọ lo rán an wá.

  (ÈGBÈ)

  O fún wa l’Ọ́mọ rẹ,

  A sì ń  kọrin yìn ọ́,

  A  ó máa yìn ọ́ títí láé,

  fún bó  o ṣe fún wa l’Ọ́mọ rẹ.

  (ÌPARÍ)

  Jèhófà, Baba wa, ọkàn wa kún f’ọ́pẹ́.

  A dúpẹ́ tó  o fún wa ní Ọmọ rẹ kan ṣoṣo.