Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kọrin sí Jèhófà—Àwọn Orin Tuntun

 Orin 143

Ìmọ́lẹ̀ Nínú Ayé Tó Ṣókùnkùn

Ìmọ́lẹ̀ Nínú Ayé Tó Ṣókùnkùn

Wà á jáde:

(2 Kọ́ríńtì 4:6)

 1. Láyé burúkú tá a wà yìí,

  Ìmọ́lẹ̀ wà tá à ń rí.

  Bíi pé ojúmọ́ ń mọ́ bọ̀

  Tó máa mọ́ kedere.

  (ÈGBÈ)

  Iṣẹ́ ìwàásù wa,

  Mọ́lẹ̀ nínú òkùnkùn.

  Ó ń mú ìrètí wá—

  Ó ń mọ́lẹ̀, ó ń tàn yòò,

  Ó ń mú ká lè rí ọ̀la—

  Òkùnkùn lọ.

 2. Ó yẹ ká jí àwọn tó ń sùn

  Torí àkókò ń lọ.

  À ń gbé wọn ró, wọ́n ń nírètí.

  À ń fi wọ́n sádùúrà.

  (ÈGBÈ)

  Iṣẹ́ ìwàásù wa,

  Mọ́lẹ̀ nínú òkùnkùn.

  Ó ń mú ìrètí wá—

  Ó ń mọ́lẹ̀, ó ń tàn yòò,

  Ó ń mú ká lè rí ọ̀la—

  Òkùnkùn lọ.