Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kọrin sí Jèhófà—Àwọn Orin Tuntun

 Orin 138

Jèhófà Ni Orúkọ Rẹ

Jèhófà Ni Orúkọ Rẹ

Wà á jáde:

(Sáàmù 83:18)

 1. Ọlọ́run alààyè—

  Ọlọ́run ohun gbogbo

  Láti ìran dé ìran—

  Jèhófà loókọ rẹ.

  O dá wa lọ́lá gan-an

  A ń yọ̀ p’a jẹ́ èèyàn rẹ.

  À ń kéde ògo rẹ fún,

  Ẹ̀yà orílẹ̀èdè.

  (ÈGBÈ)

  Jèhófà, Jèhófà,

  Kò s’Ọlọ́run bí ‘rẹ.

  Kò sẹ́lòmíì lọ́run bí ‘rẹ

  Tàbí láyé níbí.

  Ìwọ ni Olódùmarè,

  Aráyé gbọ́dọ̀ mọ̀.

  Jèhófà, Jèhófà,

  Ìwọ nìkan l’Ọlọ́run wa.

 2. Ìwọ mú kí a di

  Ohunkóhun tí o fẹ́,

  Ka lè ṣohun tí o fẹ́—

  Jèhófà loókọ rẹ.

  Nítorí àánú rẹ

  O pè wá l’Ẹ́lẹ́rìí rẹ.

  O dá wa lọ́lá torí—

  À ń jẹ́ orúkọ rẹ.

  (ÈGBÈ)

  Jèhófà, Jèhófà,

  Kò s’Ọlọ́run bí ‘rẹ.

  Kò sẹ́lòmíì lọ́run bí ‘rẹ

  Tàbí láyé níbí.

  Ìwọ ni Olódùmarè,

  Aráyé gbọ́dọ̀ mọ̀.

  Jèhófà, Jèhófà,

  Ìwọ nìkan l’Ọlọ́run wa.

(Tún wo 2 Kíró. 6:14; Sm. 72:19; Aísá. 42:8.)