Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kọrin sí Jèhófà—Àwọn Orin Tuntun

Gbádùn àwọn orin tuntun tá a fi ń yin Jèhófà Ọlọ́run, tá a sì fi ń jọ́sìn rẹ̀. Wa orin àti ọ̀rọ̀ orin jáde, kó o sì máa fi àwọn orin alárinrin yìí dánra wò.

Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso—Jẹ́ Kó Dé!

A ń fi orin Ìjọba Ọlọ́run tó ládùn yìí yin Jèhófà fún ìṣàkóso Ìjọba rẹ̀ látọwọ́ Jésù Kristi.

Fún Wá Ní Ìgboyà

Maa ko orin yii ta a fi n be Jehofa Olorun pe ko fun wa ni igboya ka le maa soro ni oruko re.

Jèhófà Ni Orúkọ Rẹ

Maa yin oruko ologo Jehofa, ko o si je ki araye mo pe oun ni Eni Giga Ju Lo.

Kọ́ Wọn Kí Wọ́n Lè Dúró Gbọn-in

À ń bẹ Jèhófà pé kó dáàbò bò wá, kó sì ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ olóòótọ́ ká sì ní ìfaradà bá a ṣe ń sá eré ìje ìyè.

Ìgbé Ayé Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà

Kọ orin yìí láti fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà látọkànwá, kó o sì fi hàn pé o fẹ́ràn iṣẹ́ ìwàásù àti ìgbésí ayé tó o yàn.

À Ń Wá Àwọn Ọ̀rẹ́ Àlàáfíà

Orin atunilára tó ń múnú ẹni dùn tó dá lórí bí a ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn àti bá a ṣe ń fara balẹ̀ wá àwọn àgùntàn Ọlọ́run tó ṣeyebíye.

À Ń Wàásù fún Gbogbo Onírúurú Èèyàn

Kọ orin tó dá lórí bí Jèhófà ṣe jẹ́ ẹni rere àti bí a ṣe ń kí onírúuru èèyàn tó fẹ́ di ọ̀rẹ́ Jèhófà káàbọ̀.

Ìmọ́lẹ̀ Nínú Ayé Tó Ṣókùnkùn

Iṣẹ́ ìwàásù wa ń mọ́lẹ̀ nínú òkùnkùn.

Wọ́n Á Rí Ìgbàlà

Ó yẹ ká sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn torí àkókò ṣì wà báyìí.

À Ń Múra Láti Lọ Wàásù

Ó lè wù wá ká dúró sílé, àmọ́ a lè lókun ká lè ṣàṣeyọrí.

Èmi Lẹ Ṣe É Fún

Jésù gbà pé òun la ṣe é fún tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin rẹ̀ tó jẹ́ ẹni àmì òróró, tá a sì tì wọ́n lẹ́yìn.

Àkànṣe Dúkìá

Jèhófà mọyì àwọn ọmọ rẹ̀ tó fi ẹ̀mí yàn, àwọn náà sì fẹ́ràn láti máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́.

O Fún Wa Ní Ọmọ Rẹ Kan Ṣoṣo

Dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ẹ̀bùn tó ṣeyebíye jù lọ tó fún wa. Ẹ̀bùn yìí jẹ́ kí gbogbo èèyàn ní ìrètí.

A Dúpẹ́ fún Ìràpadà

Ìràpadà ni ọ̀nà tó ga jù lọ tí Jèhófà gbà fi ìfẹ́ hàn sí wa. Títí ayé ni a ó máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún bí Jésù ṣe fi tinútinú kú fún wa.

Wá Wọn Lọ

Máa fi ayọ̀ sin Jèhófà lọ́nà tó fẹ́, kó o sì pinnu láti sìn níbi tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu.

Ọlọ́run Máa Ṣí Àwọn Ọmọ Rẹ̀ Payá

À ń retí ọjọ́ tí Jèhófà máa gbé àwọn arákùnrin Kristi dìde sí ọ̀run kí àwọn àti Jésù lè jọ ṣẹ́gun kí wọ́n sì jọ gba èrè.

Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbẹ́kẹ̀lé Wa

Tí àwọn ìṣòro ìgbésí ayé bá mú ki ẹ̀rù máa bà wá, Ọlọ́run máa fún wa ní agbára àti ìrètí, á sì jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀.

Báwo Ló Ṣe Rí Lára Rẹ?

Báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ tó o bá ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti wá àwọn ẹni yíyẹ kàn?

A Ó Máa Fara Dà Á Nìṣó

Orin tó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa fara da ìṣòro, ká sì máa fòótọ́ sin Jèhófà nìṣó.