Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORIN 95

Ìmọ́lẹ̀ Náà Ń Mọ́lẹ̀ Sí I

Yan Àtẹ́tísí
Ìmọ́lẹ̀ Náà Ń Mọ́lẹ̀ Sí I
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Òwe 4:18)

 1. 1. Àwọn wòlíì àtijọ́ fẹ́ mọ Kristi,

  Ẹni tó jẹ́ káyé nírètí.

  Ẹ̀mí Ọlọ́run jẹ́rìí sí i pé yóò wá,

  Yóò jẹ́ káráyé rítùúsílẹ̀.

  Ní báyìí, Mèsáyà ti ń jọba lọ́run,

  Ẹ̀rí tó dájú fèyí hàn.

  Àǹfààní ló jẹ́ láti m’òtítọ́ yìí,

  Òótọ́ táwọn áńgẹ́lì fẹ́ mọ̀!

  (ÈGBÈ)

  Ipa ọ̀nà wa ti ń mọ́lẹ̀ sí i

  Bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀sán gangan.

  Ọlọ́run ń ṣí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ payá;

  Ó ń tọ́ wa sọ́nà tá ó máa rìn.

 2. 2. Ẹrú olóòótọ́ tí Jésù yàn sípò,

  Ń fún wa lóúnjẹ lákòókò tó yẹ.

  Ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

  Ló ń fa olóòótọ́ ọkàn mọ́ra.

  Ìmọ́lẹ̀ túbọ̀ ń tàn sípa ọ̀nà wa,

  Ẹsẹ̀ wa kò kúrò lọ́nà.

  A dúpẹ́, Jèhófà, Orísun ‘mọ́lẹ̀,

  Títí láé la ó máa rìn lọ́nà rẹ.

  (ÈGBÈ)

  Ipa ọ̀nà wa ti ń mọ́lẹ̀ sí i

  Bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀sán gangan.

  Ọlọ́run ń ṣí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ payá;

  Ó ń tọ́ wa sọ́nà tá ó máa rìn.