Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORIN 9

Jèhófà Ni Ọba Wa!

Yan Àtẹ́tísí
Jèhófà Ni Ọba Wa!
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Sáàmù 97:1)

 1. 1. Ẹ yọ̀, ẹ fògo fún Jèhófà

  Tor’áwọn ọ̀run ń sọ̀rọ̀ òdodo rẹ̀.

  Ẹ jẹ́ ká forin ayọ̀ yin Ọlọ́run wa;

  Ká sọ àwọn iṣẹ́ ‘yanu rẹ̀.

  (ÈGBÈ)

  Jẹ́ kí ọ̀run máa yọ̀, kílẹ̀ ayé sì dùn,

  Torí Jèhófà ti dọba wa!

  Jẹ́ kí ọ̀run máa yọ̀, kílẹ̀ ayé sì dùn,

  Torí Jèhófà ti dọba wa!

 2. 2. Ẹ ròyìn ògo rẹ̀ fáráyé;

  Jèhófà Ọlọ́run l’Olùgbàlà wa.

  Jèhófà l’Ọba wa tó yẹ ká fìyìn fún.

  A tẹrí ba ní iwájú rẹ̀.

  (ÈGBÈ)

  Jẹ́ kí ọ̀run máa yọ̀, kílẹ̀ ayé sì dùn,

  Torí Jèhófà ti dọba wa!

  Jẹ́ kí ọ̀run máa yọ̀, kílẹ̀ ayé sì dùn,

  Torí Jèhófà ti dọba wa!

 3. 3. Ó fi Ọmọ rẹ̀ sórí ìtẹ́,

  Ìṣàkóso rẹ̀ sì ti fìdí múlẹ̀.

  Kí ojú ti àwọn ọlọ́run ayé yìí,

  Jèhófà nìkan ni ìyìn yẹ.

  (ÈGBÈ)

  Jẹ́ kí ọ̀run máa yọ̀, kílẹ̀ ayé sì dùn,

  Torí Jèhófà ti dọba wa!

  Jẹ́ kí ọ̀run máa yọ̀, kílẹ̀ ayé sì dùn,

  Torí Jèhófà ti dọba wa!