Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

“Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà

 ORIN 85

Ẹ Fayọ̀ Tẹ́wọ́ Gba Ara Yín

Yan Àtẹ́tísí
Ẹ Fayọ̀ Tẹ́wọ́ Gba Ara Yín
WÒÓ
Ọ̀rọ̀

(Róòmù 15:7)

 1. 1. A kí yín káàbọ̀ sí Gbọ̀ngàn ‘jọba,

  Gbogbo ẹ̀yin tẹ́ ẹ wá jọ́sìn Jáà.

  Ìpèsè oúnjẹ tẹ̀mí wà fún wa;

  Ìpéjọ wa ládùn, ó lóyin, à ń kẹ́kọ̀ọ́.

 2. 2. A mọrírì àwọn arákùnrin

  Tó ń múpò ‘wájú nínú ìjọ.

  Ẹni ọ̀wọ́n tí Jáà fún wa ni wọ́n,

  Bí wọ́n ṣe ń bójú tó iṣẹ́ táa yàn fún wọn.

 3. 3. À ń ké sí gbogbo orílẹ̀-èdè

  Kí wọ́n lè wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.

  Jèhófà àti Jésù ló ń fà wá;

  Ká fi tọkàntọkàn tẹ́wọ́ gba ara wa.