WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Mátíù 9:37, 38)

 1. 1. Jèhófà mọ àwọn ohun

  Tó máa fún wa láyọ̀ tòótọ́.

  Ó wá pèsè ọ̀pọ̀ ọ̀nà

  Tá a lè fi sìn ín, ká ṣiṣẹ́ rẹ̀.

  (ÈGBÈ)

  Wá wọn lọ, sapá gan-an,

  ṣiṣẹ́ Ọlọ́run.

  A ṣe tán láti lọ sìn níbi

  tí àìní bá wà.

 2. 2. Iṣẹ́ pọ̀ fún wa láti ṣe

  Ní gbogbo orílẹ̀-èdè.

  À ń yọ̀ǹda ara wa láti

  Ṣèrànlọ́wọ́ fáwọn èèyàn.

  (ÈGBÈ)

  Wá wọn lọ, sapá gan-an,

  ṣiṣẹ́ Ọlọ́run.

  A ṣe tán láti lọ sìn níbi

  tí àìní bá wà.

 3. 3. Lágbègbè wa, à ń ṣèrànwọ́

  Fáwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé.

  A sì tún máa ń kọ́ èdè mí ì,

  Kí aráyé lè gbọ́ ‘wàásù.

  (ÈGBÈ)

  Wá wọn lọ, sapá gan-an,

  ṣiṣẹ́ Ọlọ́run.

  A ṣe tán láti lọ sìn níbi

  tí àìní bá wà.