Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORIN 81

Ìgbésí Ayé Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà

Yan Àtẹ́tísí
Ìgbésí Ayé Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Oníwàásù 11:6)

 1. 1. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, tí oòrùn kò tí ì yọ,

  Ọkàn wa wà níbi

  iṣẹ́ Jáà tá a pinnu láti ṣe.

  À ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fáyé, pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́;

  Àwọn kan ń gbọ́rọ̀ wa,

  báwọn kan kò tiẹ̀ wobi tá a wà.

  (ÈGBÈ)

  Iṣẹ́ tá a yàn nìyí,

  Ìfẹ́ Jáà la fẹ́ ṣe.

  Ohun tó fẹ́ ká ṣe lá ó máa ṣe.

  Bóòrùn ń ràn, bójò ń rọ̀,

  Kò ṣèdíwọ́ fún wa.

  Èyí la fi ń fi hàn pá a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.

 2. 2. Nígbà tílẹ̀ bá ṣú, tá a bojú wẹ̀yìn wò,

  bó tiẹ̀ lè ti rẹ̀ wá,

  Inú wa ń dùn, a sì ń gbàdúrà.

  Jèhófà ń bù kún wa lójoojúmọ́ ayé.

  À ń sun oorun ayọ̀,

  à ń jí sáyé, a fọpẹ́ fún Jáà.

  (ÈGBÈ)

  Iṣẹ́ tá a yàn nìyí,

  Ìfẹ́ Jáà la fẹ́ ṣe.

  Ohun tó fẹ́ ká ṣe lá ó máa ṣe.

  Bóòrùn ń ràn, bójò ń rọ̀,

  Kò ṣèdíwọ́ fún wa.

  Èyí la fi ń fi hàn pá a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.