WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Mátíù 28:19, 20)

 1. 1. Inú wa dùn pé à ń kọ́ àwọn

  Àgùntàn ti Jèhófà.

  Ààbò rẹ̀ dájú fún àwọn tó

  Sọ òtítọ́ di tiwọn.

  (ÈGBÈ)

  Bàbá wa ọ̀run, Jèhófà,

  Jọ̀ọ́, fẹ̀mí rẹ dáàbò bò wọ́n,

  Lórúkọ Jésù Ọmọ Rẹ, là ń gbàdúrà;

  Kí wọ́n lè ṣe àṣeyọrí.

 2. 2. Bá a ṣe ń kọ́ wọn lọ́rọ̀ Ọlọ́run,

  A máa ń gbàdúrà fún wọn.

  Wọ́n ń kojú àdánwò, wọ́n ńborí;

  Wọ́n ń lókun, Jáà ń bù kún wọn.

  (ÈGBÈ)

  Bàbá wa ọ̀run, Jèhófà,

  Jọ̀ọ́, fẹ̀mí rẹ dáàbò bò wọ́n,

  Lórúkọ Jésù Ọmọ Rẹ, là ń gbàdúrà;

  Kí wọ́n lè ṣe àṣeyọrí.

 3. 3. Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run

  Àti Ọmọ rẹ̀ Jésù;

  Ìgbọràn àti ìfaradà

  Máa jẹ́ kí wọ́n rí ìyè.

  (ÈGBÈ)

  Bàbá wa ọ̀run, Jèhófà,

  Jọ̀ọ́, fẹ̀mí rẹ dáàbò bò wọ́n,

  Lórúkọ Jésù Ọmọ Rẹ, là ń gbàdúrà;

  Kí wọ́n lè ṣe àṣeyọrí.