Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORIN 70

Ẹ Wá Àwọn Ẹni Yíyẹ Kàn

Yan Àtẹ́tísí
Ẹ Wá Àwọn Ẹni Yíyẹ Kàn
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Mátíù 10:11-15)

 1. 1. Kristi kọ́ wa bá a ṣe máa fòótọ́ kọ́ni

  Àti bí a ó ṣe máa wàásù.

  Ó sọ pé: ‘Ẹ wá àwọn ẹni yíyẹ

  Tó ṣe tán láti kẹ́kọ̀ọ́ òótọ́.

  Tẹ́ ẹ bá délé kan, kí ẹ kọ́kọ́ kí wọn,

  Kí ẹ bá wọn sọ̀rọ̀ àlàáfíà.

  Ṣùgbọ́n tí wọ́n bá sọ pé àwọn ò gbọ́,

  Ẹ kúrò, ẹ lọ síbòmíràn.’

 2. 2. Ẹ bá àwọn tó tẹ́wọ́ gbà yín sọ́rọ̀;

  Ẹ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.

  Wọ́n máa gbọ́ torí pé wọ́n lọ́kàn tó dáa.

  Láìpẹ́, àwọn náà yóò wá sin Jáà.

  Má ṣe dààmú torí ohun tó o máa sọ;

  Jèhófà yóò fi sí ọ lẹ́nu.

  Tó o bá ń sọ̀rọ̀ tó dáa, tó ń tuni lára,

  Yóò mú kí onírẹ̀lẹ̀ fẹ́ gbọ́.