Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORIN 7

Jèhófà Ni Agbára Wa

Yan Àtẹ́tísí
Jèhófà Ni Agbára Wa
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Aísáyà 12:2)

 1. 1. Okun wa, agbára wa, ààbò wa;

  Jèhófà, ayọ̀ wa, ìgbàlà wa.

  A ó fayọ̀ sọ nípa rẹ fáráyé,

  Bóyá wọ́n fẹ́ gbọ́ tàbí wọn kò fẹ́.

  (ÈGBÈ)

  Ìwọ l’Àpáta wa àt’Okun wa,

  A ó jẹ́ káráyé morúkọ rẹ.

  Jèhófà, ìwọ lo lágbára jù,

  Ìwọ nibi ààbò wa gíga jù.

 2. 2. Ẹlẹ́rìí rẹ tá a jẹ́ ńmú ká láyọ̀.

  A mọ òtítọ́ àtohun tó tọ́.

  Àṣẹ rẹ tó wà nínú Bíbélì

  Mú ká lè kọ́wọ́ ti Ìjọba rẹ.

  (ÈGBÈ)

  Ìwọ l’Àpáta wa àt’Okun wa,

  A ó jẹ́ káráyé morúkọ rẹ.

  Jèhófà, ìwọ lo lágbára jù,

  Ìwọ nibi ààbò wa gíga jù.

 3. 3. Bí Èṣù ń gàn wá, a kò ní bẹ̀rù

  Títí láé la ó máa fayọ̀ ṣèfẹ́ rẹ.

  Bí Sátánì bá tiẹ̀ fẹ́ gbẹ̀mí wa,

  Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí ọ.

  (ÈGBÈ)

  Ìwọ l’Àpáta wa àt’Okun wa,

  A ó jẹ́ káráyé morúkọ rẹ.

  Jèhófà, ìwọ lo lágbára jù,

  Ìwọ nibi ààbò wa gíga jù.