Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORIN 58

À Ń Wá Àwọn Ọ̀rẹ́ Àlàáfíà

Yan Àtẹ́tísí
À Ń Wá Àwọn Ọ̀rẹ́ Àlàáfíà
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Lúùkù 10:6)

 1. 1. Jésù pàṣẹ pé: ‘Ẹ wàásù òótọ́.’

  Lójò lẹ́ẹ̀rùn ló máa ń wàásù

  látòwúrọ̀, tílẹ̀ fi ṣú.

  Ó ń pe àwọn èèyàn níbi gbogbo.

  Ó nífẹ̀ẹ́ wọn, ó sì ń kọ́ wọn

  lọ́rọ̀ Ọlọ́run.

  Nílé délé, lójú ọ̀nà,

  À ń wàásù fún gbogbo èèyàn

  Pé ìṣòro aráyé máa tó dópin.

  (ÈGBÈ)

  Kárí ayé,

  À ń wá àwọn ọ̀rẹ́ àlàáfíà.

  A sì tún ń wá

  Àwọn èèyàn tó fẹ́ ìgbàlà.

  Gbogbo ‘pá wa

  Ni a máa sà.

 2.  2. Ká tẹra mọ́ ‘wàásù, àkókò ń lọ,

  Ká sì fi kún ìsapá wa

  kọ́pọ̀ èèyàn lè rígbàlà.

  Ìfẹ́ ló ń mú ká pa dà wá wọn lọ.

  Ká lè ràn wọ́n lọ́wọ́, ká sì

  tún ayé wọn ṣe.

  Nílùú délùú, níbi gbogbo,

  Tá a bá rẹ́ni tó gbọ́rọ̀ wa,

  Inú wa máa ń dùn, a sì máa ń báṣẹ́ lọ.

  (ÈGBÈ)

  Kárí ayé,

  À ń wá àwọn ọ̀rẹ́ àlàáfíà.

  A sì tún ń wá

  Àwọn èèyàn tó fẹ́ ìgbàlà.

  Gbogbo ‘pá wa

  Ni a máa sà.