Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

“Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà

 ORIN 55

Ẹ Má Bẹ̀rù Wọn!

Yan Àtẹ́tísí
Ẹ Má Bẹ̀rù Wọn!
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Mátíù 10:28)

 1. 1. Èèyàn mi, ẹ tẹ̀ síwájú,

  Ẹ wàásù Ìjọba náà.

  Ẹ má ṣe bẹ̀rù ọ̀tá.

  Ẹ jẹ́ kí aráyé mọ̀

  Pé Jésù Ọmọ mi, Ọba

  Ti lé ọ̀tá jù sáyé.

  Láìpẹ́, yóò mú Èṣù, yóò sì

  Tú àwọn tó dè sílẹ̀.

  (ÈGBÈ)

  Ẹ má bẹ̀rù àwọn ọ̀tá

  Bí wọ́n tiẹ̀ ń halẹ̀ mọ́ yín.

  Èmi yóò pa olóòótọ́ mọ́

  Gẹ́gẹ́ bí ẹyinjú mi.

 2. 2. Bí àwọn ọ̀tá yín tiẹ̀ pọ̀,

  Tí wọ́n sì ń halẹ̀ mọ́ yín,

  Tí wọ́n ń fi yín ṣẹlẹ́yà,

  Kí wọ́n lè ṣì yín lọ́nà,

  Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin tèmi

  Bí wọ́n tiẹ̀ ń fìyà jẹ yín.

  Èmi yóò pa olóòótọ́ mọ́

  Títí wọn yóò fi ṣẹ́gun.

  (Ègbè)

  Ẹ má bẹ̀rù àwọn ọ̀tá

  Bí wọ́n tiẹ̀ ń halẹ̀ mọ́ yín.

  Èmi yóò pa olóòótọ́ mọ́

  Gẹ́gẹ́ bí ẹyinjú mi.

 3.  3. Má ṣe rò pé mo pa ọ́ tì,

  Èmi ṣì ni ààbò rẹ.

  Tó bá ṣẹlẹ̀ pé o kú,

  Èmi yóò jí ọ dìde.

  Má bẹ̀rù àwọn tó ń para,

  Tí wọn kò lè pa ọkàn.

  Jẹ́ olóòótọ́ títí dópin,

  Màá fún ọ ládé ìyè!

  (Ègbè)

  Ẹ má bẹ̀rù àwọn ọ̀tá

  Bí wọ́n tiẹ̀ ń halẹ̀ mọ́ yín.

  Èmi yóò pa olóòótọ́ mọ́

  Gẹ́gẹ́ bí ẹyinjú mi.