Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORIN 52

Ìyàsímímọ́ Kristẹni

Yan Àtẹ́tísí
Ìyàsímímọ́ Kristẹni
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Hébérù 10:7, 9)

 1. 1. Jèhófà Ọlọ́run ṣẹ̀dá

  Àgbáálá ayé yìí.

  Tirẹ̀ layé àti ọ̀run,

  Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni.

  Ó fún wa ní èémí ìyè,

  Ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé,

  Òun nìkan ló yẹ ká fìyìn fún,

  Òun nìkan ló yẹ ká sìn.

 2. 2. Jésù Kristi ṣèrìbọmi

  Láti módodo ṣẹ.

  Ó gbàdúrà s’Ọ́lọ́run pé:

  ‘Mo dé wá ṣèfẹ́ rẹ.’

  Bó ṣe jáde nínú omi,

  Ọlọ́run fẹ̀mí yàn án.

  Olóòótọ́ ni, ó gbàdúrà pé:

  ‘Bàbá, jẹ́ kífẹ̀ẹ́ rẹ ṣẹ.’

 3. 3. Iwájú rẹ la wà, Bàbá.

  À ń yin orúkọ rẹ.

  A ya ara wa sí mímọ́

  Pẹ̀lú ‘rẹ̀lẹ̀ ọkàn.

  O fún wa lọ́mọ bíbí rẹ;

  Ó fẹ̀mí rẹ̀ rúbọ.

  Torí náà, ìfẹ́ Rẹ lá ó máa ṣe

  Jálẹ̀ ọjọ́ ayé wa.