Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORIN 5

Àwọn Iṣẹ́ Àgbàyanu Ọlọ́run

Yan Àtẹ́tísí
Àwọn Iṣẹ́ Àgbàyanu Ọlọ́run
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Sáàmù 139)

 1. 1. Ọlọ́run fagbára rẹ̀ dá mi,

  Ó mọ̀ mí gan-an ju bí mo ṣe rò lọ.

  Ó sì rí mi nínú ikùn ìyá mi;

  Bí a ṣe bí mi, tí mò ń rìn,

  tí mò ń sọ̀rọ̀.

  Bí mo ṣe ń dìde, tí mò ń jókòó,

  Bí mo ṣe ń sùn àti bí mo ṣe ń jí,

  Àmọ̀dunjú ni gbogbo rẹ̀ jẹ́ fún ọ;

  Èmi yóò gbé ọ lárugẹ,

  màá sì yìn ọ́.

  Ìmọ̀ rẹ pọ̀, ó sì kọjá òye mi;

  Àgbàyanu ni èyí jẹ́ fún mi.

  Bí mo bá sì sá lọ sínú òkùnkùn,

  Ìwọ lè fi ẹ̀mí rẹ wá mi rí.

  Kò sí ibi tí mo lè sá lọ

  Tàbí tí mo lè fara pa mọ́ sí.

  Ì báà jẹ́ ‘nú ibojì tàbí òkun

  Ibikíbi tí mo bá wà,

  o lè rí mi.