WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Sáàmù 4:1)

 1. 1. Ẹ̀dùn ọkàn mi pọ̀, ọrùn wọ̀ mí,

  ayé sú mi.

  Jèhófà, jọ̀wọ́, “Gbọ́ àdúrà mi,”

  ràn mí lọ́wọ́.

  Àròkàn mú mi sọ̀rètí nù,

  mo rora mi pin.

  Ọlọ́run ìtùnú, jọ̀ọ́ fi

  ojúure hàn sí mi.

  (ÈGBÈ)

  Fún mi lókun, kí n má bọ́hùn,

  Tíyèméjì bá fẹ́ bò mí.

  Ràn mí lọ́wọ́; mo sá di ọ́.

  Ọlọ́run mi, fún mi lókun.

 2. 2. Bíbélì máa ń tù mí nínú

  tí mo bá rẹ̀wẹ̀sì.

  Ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ tí mò ń kà

  máa ń mọ́kàn mi fúyẹ́.

  Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé ọ,

  kí n sì nígbàgbọ́.

  Kí n mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ mi gan-an

  ju bí mo ṣe rò lọ.

  (ÈGBÈ)

  Fún mi lókun, kí n má bọ́hùn,

  Tíyèméjì bá fẹ́ bò mí.

  Ràn mí lọ́wọ́; mo sá di ọ́.

  Ọlọ́run mi, fún mi lókun.