Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORIN 40

Ti Ta Ni A Jẹ́?

Yan Àtẹ́tísí
Ti Ta Ni A Jẹ́?
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Róòmù 14:8)

 1. 1. Ti ta ni ìwọ jẹ́?

  Ọlọ́run wo ni ò ń sìn?

  Ẹni tí o bá ń ṣègbọràn sí

  L’ọlọ́run rẹ, tó ń darí rẹ.

  Kò ṣeé ṣe láti sin

  Ọlọ́run méjì pa pọ̀.

  Ohun tó bá wà lọ́kàn rẹ ló máa

  Pinnu èyí tó o máa yàn.

 2. 2. Ti ta ni ìwọ jẹ́?

  Ọlọ́run wo ni ò ń sìn?

  Ọ̀kan jẹ́ òótọ́, ọ̀kan jékèé.

  Yan èyí tó o fẹ́ fúnra rẹ.

  Ṣé Ọba ayé yìí

  Lo ṣì ń fi ọkàn rẹ sìn?

  Àbí wàá sin Ọlọ́run òtítọ́,

  Kó o sì máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀?

 3. 3. Ti ta ni èmi jẹ́?

  Jáà ni màá ṣègbọràn sí.

  Bàbá mi ọ̀run lèmi yóò sìn.

  Màá san gbogbo ẹ̀jẹ́ mi fún un.

  Iye ńlá ló rà mí;

  Tọkàntọkàn ni màá sìn ín.

  Gbogbo ọjọ́ ayé mi ni màá fi

  Gbé orúkọ ńlá rẹ̀ ga.