WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Sáàmù 23)

 1. 1. Jèhófà ni Olùṣọ́ mi;

  Ọkàn mi balẹ̀ pẹ̀sẹ̀.

  Ìfẹ́ tòótọ́ tó fi hàn sí mi

  Ló mú mi wà lálàáfíà.

  Oúnjẹ tẹ̀mí rẹ̀ gbé mi ró,

  Ó fún mi lókun tó yẹ.

  Ó mú mi mọ ọ̀nà òtítọ́ rẹ̀,

  Kí nlè máa gbénú ‘lé rẹ̀.

  Ó mú mi mọ ọ̀nà òtítọ́,

  Kí n lè máa gbénú ‘lé rẹ̀.

 2. 2. Ìtura àìlẹ́gbẹ́ lèyí;

  Ọ̀nà òdodo Rẹ̀ pọ̀.

  Olùṣọ́ Àgbà ni Jèhófà,

  Kò ní jẹ́ kí n ṣáko lọ.

  B’Éṣù tilẹ̀ halẹ̀ mọ́ mi,

  ‘Jáà ń fọ̀pá rẹ̀ darí mi’

  Síbi tí kò ní sí ìbẹ̀rù mọ́,

  Tí kò ní sípayà mọ́;

  Síbi tí kò ní síbẹ̀rù mọ́,

  Tí kò ní sípayà mọ́.

 3.  3. Jèhófà jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́,

  Ẹni tó ṣeé fi yangàn.

  Ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ dá mi lójú;

  Kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn.

  Bàbá aláàánú ni Jáà jẹ́,

  Tí kì í fọ̀rọ̀ mi ṣeré.

  Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ máa ṣamọ̀nà mi

  Sípa ọ̀nà òdodo.

  Jẹ́ kífẹ̀ẹ́ rẹ máa ṣamọ̀nà mi

  Sípa ọ̀nà òdodo.

(Tún wo Sm. 28:9; 80:1.)