WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Òwe 4:23)

 1. 1. Ká máa dáàbò bo ọkàn wa

  Tí a bá fẹ́ ríyè.

  Ọlọ́run ń yẹ ọkàn wa wò,

  Ó mọ ẹni tá a jẹ́.

  Tá a bá jẹ́ kọ́kàn wa tàn wá,

  Ó lè ṣì wá lọ́nà.

  Ká jẹ́ kí èrò inú wa

  Bá ti Jèhófà mu.

 2. 2. À ń gbàdúrà tó tọkàn wá,

  À ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jáà.

  Ìgbà gbogbo là ń fìyìn fún un

  Torí pó ń tọ́jú wa.

  À ń ṣègbọràn sáwọn ẹ̀kọ́

  Tí Jèhófà ń kọ́ wa.

  Tọkàntọkàn là ń ṣèfẹ́ rẹ̀;

  A dúró ṣinṣin sí i.

 3. 3. Ohun tó tọ́ là ń fọkàn rò,

  À ń sá féròkerò.

  À ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,

  Ayé wa ń dára sí i.

  Ọkàn wa balẹ̀ torí pé

  Jáà fẹ́ràn olóòótọ́.

  A ó máa fi tọkàntọkàn sìn ín

  Títí ayérayé.