Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

“Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà

 ORIN 35

Máa Ṣe “Àwọn Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù”

Yan Àtẹ́tísí
Máa Ṣe “Àwọn Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù”
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Fílípì 1:10)

 1. 1. A nílò ìfòyemọ̀ gan-an lónìí

  Ká lè mọ ohun tó tọ́;

  Àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù

  Tí a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe.

  (ÈGBÈ)

  Nífẹ̀ẹ́ ire; Sá fún ibi.

  Múnú Jáà dùn.

  Yóò bù kún wa bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì

  Nífòyemọ̀,

  Tá à ń ṣohun tó ṣe pàtàkì jù!

 2. 2. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé

  Ká wàásù ìhìn rere.

  Ká kọ́ àwọn tó fẹ́ràn òtítọ́

  Kí wọ́n ṣèfẹ́ Ọlọ́run.

  (ÈGBÈ)

  Nífẹ̀ẹ́ ire; Sá fún ibi.

  Múnú Jáà dùn.

  Yóò bù kún wa bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì

  Nífòyemọ̀,

  Tá à ń ṣohun tó ṣe pàtàkì jù!

 3. 3. Tá a bá ń ṣohun tó ṣe pàtàkì jù,

  Ọkàn wa máa balẹ̀ gan-an.

  Àlàáfíà Ọlọ́run wa yóò máa ṣọ́

  Ọkàn àti èrò wa.

  (ÈGBÈ)

  Nífẹ̀ẹ́ ire; Sá fún ibi.

  Múnú Jáà dùn.

  Yóò bù kún wa báa ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì

  Nífòyemọ̀,

  Tá à ń ṣohun tó ṣe pàtàkì jù!