WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Sáàmù 26)

 1. 1. Ṣèdájọ́ mi, wo ìwà títọ́ mi.

  ’Wọ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé, mo jólóòótọ́ sí ọ.

  Jọ̀ọ́, yẹ̀ mí wò, kí o sì dán mi wò.

  Tún yọ́ ọkàn mi mọ́, kí n lè gba ìbùkún.

  (ÈGBÈ)

  Ní tèmi o, mo ti pinnu wí pé:

  Màá rìn títí ayé nínú ìwà títọ́.

 2. 2. Èmi kò bá ẹni ibi jókòó.

  Mo kórìíra àwọn tí kò fẹ́ òtítọ́.

  Jèhófà, jọ̀ọ́, má jẹ́ kí n kú pẹ̀lú

  Àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún ìwà ibi.

  (ÈGBÈ)

  Ní tèmi o, mo ti pinnu wí pé:

  Màá rìn títí ayé nínú ìwà títọ́.

 3. 3. Ó wù mí kí ń máa gbénú ilé rẹ,

  Kí n máa gbé ìjọsìn mímọ́ rẹ lárugẹ.

  Èmi yóò máa rìn yí pẹpẹ rẹ ká,

  Kí gbogbo èèyàn lè máa gbóhùn ọpẹ́ mi.

  (ÈGBÈ)

  Ní tèmi o, mo ti pinnu wí pé:

  Màá rìn títí ayé nínú ìwà títọ́.

(Tún wo Sm. 25:2.)