WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(1 Pétérù 2:9)

 1. 1. Ìṣẹ̀dá tuntun làwọn

  Ẹni àmì òróró.

  Inú ọmọ aráyé

  L’Ọlọ́run ti rà wọ́n.

  (ÈGBÈ)

  Àkànṣe ìní ni

  Wọ́n jẹ́ fún ọ, Jèhófà.

  Wọ́n fẹ́ ọ, wọ́n ń yìn ọ́.

  Wọ́n ń pòkìkí rẹ kárí ayé.

 2. 2. Orílẹ̀-èdè mímọ́

  Tó jẹ́ olóòótọ́ ni wọ́n.

  Jèhófà mú wọn kúrò

  Lókùnkùn sí ‘mọ́lẹ̀.

  (ÈGBÈ)

  Àkànṣe ìní ni

  Wọ́n jẹ́ fún ọ, Jèhófà.

  Wọ́n fẹ́ ọ, wọ́n ń yìn ọ́.

  Wọ́n ń pòkìkí rẹ kárí ayé.

 3. 3. Wọ́n ń pe àgùntàn mìíràn,

  Wọ́n sì ń kó gbogbo wọn jọ.

  Wọ́n dúró gbọn-in ti Jésù.

  Wọ́n ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.

  (ÈGBÈ)

  Àkànṣe ìní ni

  Wọ́n jẹ́ fún ọ, Jèhófà.

  Wọ́n fẹ́ ọ, wọ́n ń yìn ọ́.

  Wọ́n ń pòkìkí rẹ kárí ayé.