ORIN 24
Ẹ Wá sí Òkè Jèhófà
1. Bojú wòkè, kó o rí
Òkè ilé Jèhófà.
Ó ga ju gbogbo òkè
Mìíràn tó wà lónìí.
Láti ibi gbogbo
Jákèjádò ayé yìí,
Àwọn èèyàn ń pera wọn
Wá jọ́sìn Ọlọ́run.
Ọlọ́run ń darí wa,
Ó sì ń bù kún wa lọ́pọ̀lọpọ̀.
A sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i;
A ti di orílẹ̀-èdè ńlá.
Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé
Jèhófà lọba ‘láṣẹ.
Wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin,
Wọ́n rọ̀ mọ́ Jèhófà.
2. Jésù ti pàṣẹ pé
Ká wàásù ìhìnrere.
Ká jẹ́ kí gbogbo èèyàn
Gbọ́rọ̀ Ìjọba náà.
Kristi ń jọba lọ́run,
Ó ń pe gbogbo aráyé.
Ó ń fi Bíbélì darí
Àwọn ẹni yíyẹ.
Gbogbo wa là ń sapá
Láti jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀.
Ayọ̀ kún inú wa,
Torí ogunlọ́gọ̀ ńlá ń pọ̀ sí i.
Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa
Pe àwọn èèyàn wá sí
Òkè ilé Jèhófà;
Kí wọ́n má kúrò láé.
(Tún wo Sm. 43:3; 99:9; Aísá. 60:22; Ìṣe 16:5.)