WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Ìṣípayá 11:15)

 1. 1. Ìjọba Jáà ti bẹ̀rẹ̀.

  Ẹ yin Kristi Ọba rẹ̀.

  Olúwa wa ti ń ṣàkóso lọ́run.

  Ẹ jẹ́ ká yin Ọlọ́run,

  Kí gbogbo wa kọrin sí i,

  Torí pé ó gbé

  Kristi sórí ìtẹ́ Rẹ̀.

  (ÈGBÈ)

  Kí n’Ìjọba Jèhófà ńmú bọ̀?

  Òótọ́ àti òdodo ni.

  Nǹkan mìíràn wo ni yóò mú wá?

  Ìyè tòótọ́ àti ayọ̀.

  Ẹ yin Ọba ‘láṣẹ torí

  Ìfẹ́ àtòdodo rẹ̀.

 2. 2. Kristi ń ṣàkóso báyìí.

  Amágẹ́dọ́nì dé tán.

  Láìpẹ́, ayé Èṣù yìí máa pa run.

  Àkókò nìyí fún wa,

  Ká wàásù fónírẹ̀lẹ̀,

  Kí wọ́n lè dúró

  sọ́dọ̀ Jèhófà lónìí.

  (ÈGBÈ)

  Kí n’Ìjọba Jèhófà ńmú bọ̀?

  Òótọ́ àti òdodo ni.

  Nǹkan mìíràn wo ni yóò mú wá?

  Ìyè tòótọ́ àti ayọ̀.

  Ẹ yin Ọba ‘láṣẹ torí

  Ìfẹ́ àtòdodo rẹ̀.

 3.  3. A mọyì Ọba wa yìí

  Tí Ọlọ́run yàn fún wa.

  Jáà ló fi jọba, a sì ń bọ̀wọ̀ fún un.

  Ẹ jẹ́ ká bẹ Jèhófà

  Pé kó ṣojúure sí wa.

  Láìpẹ́, yóò máa

  jọba lórí ohun gbogbo.

  (ÈGBÈ)

  Kí n’Ìjọba Jèhófà ńmú bọ̀?

  Òótọ́ àti òdodo ni.

  Nǹkan mìíràn wo ni yóò mú wá?

  Ìyè tòótọ́ àti ayọ̀.

  Ẹ yin Ọba ‘láṣẹ torí

  Ìfẹ́ àtòdodo rẹ̀.