WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Mátíù 6:33)

 1. 1. Ohun kan tó ṣeyebíye,

  Tó ń mú Jèhófà láyọ̀,

  Ni Ìjọba Jésù Kristi

  Tó máa mú ìfẹ́ Rẹ̀ ṣẹ.

  (ÈGBÈ)

  Ẹ kọ́kọ́ wá Ìjọba náà

  Àtòdodo Jèhófà.

  Ká pòkìkí rẹ̀ fáráyé,

  Ká sì máa fòtítọ́ sìn ín.

 2. 2. Má jẹ́ k’áníyàn rẹ pọ̀ jù;

  ‘Kí la máa jẹ, kí la ó mu?’

  Jèhófà máa pèsè fún wa,

  Ká fi tirẹ̀ sákọ̀ọ́kọ́.

  (ÈGBÈ)

  Ẹ kọ́kọ́ wá Ìjọba náà

  Àtòdodo Jèhófà.

  Ká pòkìkí rẹ̀ fáráyé,

  Ká sì máa fòtítọ́ sìn ín.

 3. 3. Ká wàásù ìhìnrere náà.

  Ká jẹ́ kí ẹni yíyẹ

  Mọ̀ pé Ìjọba Jèhófà

  Nìkan ló ṣeé gbọ́kàn lé.

  (ÈGBÈ)

  Ẹ kọ́kọ́ wá Ìjọba náà

  Àtòdodo Jèhófà.

  Ká pòkìkí rẹ̀ fáráyé,

  Ká sì máa fòtítọ́ sìn ín.