Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORIN 16

Ẹ Yin Jáà Nítorí Ọmọ Rẹ̀ Tó Fòróró Yàn

Yan Àtẹ́tísí
Ẹ Yin Jáà Nítorí Ọmọ Rẹ̀ Tó Fòróró Yàn
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Ìṣípayá 21:2)

 1. 1. Jèhófà ti yan Ọmọ rẹ̀

  Láti ṣàkóso ayé,

  Kí ìfẹ́ Rẹ̀ lè ṣẹ ní ayé;

  Ọba olódodo ló jẹ́.

  (ÈGBÈ)

  Ẹ yin Jèhófà fún Ọmọ rẹ̀,

  ẹ̀yin tó ń tẹ̀ lé àṣẹ rẹ̀;

  Gbogbo olódodo, ẹ yin Jésù,

  Ọba tí Ọlọ́run yàn.

  Ẹ yin Jèhófà fún Ọmọ rẹ̀,

  tó ń jọba nísàálú ọ̀run.

  Ó ń gbórúkọ mímọ́ Ọlọ́run ga

  Pẹ̀lú agbára ńlá rẹ̀.

 2. 2. Àwọn arákùnrin Kristi

  T’Ọ́lọ́run sọ d’àtúnbí,

  Wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù

  Láti sọ ayé di tuntun.

  (ÈGBÈ)

  Ẹ yin Jèhófà fún Ọmọ rẹ̀,

  ẹ̀yin tó ń tẹ̀ lé àṣẹ rẹ̀;

  Gbogbo olódodo, ẹ yin Jésù,

  Ọba tí Ọlọ́run yàn.

  Ẹ yin Jèhófà fún Ọmọ rẹ̀,

  tó ń jọba nísàálú ọ̀run.

  Ó ń gbórúkọ mímọ́ Ọlọ́run ga

  Pẹ̀lú agbára ńlá rẹ̀.