Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORIN 151

Òun Yóò Pè

Yan Àtẹ́tísí
Òun Yóò Pè
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Jóòbù 14:13-15)

 1. 1. Bí ìrì òwúrọ̀ lẹ̀mí wa rí,

  Tó bá dọ̀sán yóò pòórá.

  Téèyàn bá kú, ó ti dẹni àná,

  Ẹkún, òṣé yóò tẹ̀ lée.

  Tí èèyàn bá kú, ṣé ó tún lè jí?

  Gbọ́ ìlérí Ọlọ́run:

  (ÈGBÈ)

  Yóò pè wọ́n, pẹ̀lú àṣẹ rẹ̀.

  Àwọn òkú yóò sì jí.

  Jèhófà yóò ṣàfẹ́rí

  Èèyàn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

  Nígbàgbọ́, sì fọkàn balẹ̀,

  Àwọn òkú ṣì máa jí.

  Aó sì wà láàyè láéláé,

  Ìlérí Jèhófà ni.

 2. 2. Àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tó ti kú,

  Ọlọ́run kò gbàgbé wọn.

  Gbogbo wọn ni yóò ji dìde pa dà,

  Wọn yóò wà láàyè láéláé.

  Ayé á wá rí b’Ọlọ́run ṣe fẹ́:

  Párádísè títí láé.

  (ÈGBÈ)

  Yóò pè wọ́n, pẹ̀lú àṣẹ rẹ̀.

  Àwọn òkú yóò sì jí.

  Jèhófà yóò ṣàfẹ́rí

  Èèyàn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

  Nígbàgbọ́, sì fọkàn balẹ̀,

  Àwọn òkú ṣì máa jí.

  Aó sì wà láàyè láéláé,

  Ìlérí Jèhófà ni.