Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORIN 149

Orin Ìṣẹ́gun

Yan Àtẹ́tísí
Orin Ìṣẹ́gun
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(Ẹ́kísódù 15:1)

 1. 1. Ẹ kọrin ìyìn sí Jèhófà Bàbá wa lọ́run.

  Ó pa Ọba Fáráò, àtàwọn ‘mọ ogun rẹ̀.

  Olódùmarè;

  Kò sí ẹni tó lè dojú kọ ọ́.

  Jèhófà lóókọ rẹ̀;

  Òun ni ajagunṣẹ́gun.

  (ÈGBÈ)

  Jèhófà, Ọba ayérayé,

  Gbogbo ayé máa rí agbára rẹ,

  Nígbà tó o bá pàwọn ọ̀tá rẹ run,

  Wàá sọrúkọ rẹ di mímọ́.

 2. 2. Gbogbo ìjọba, ti kóra jọ, wọ́n sì ńta ko Jáà.

  Bí wọ́n ṣe lágbára tó,

  Ìtìjú yóò bá wọn.

  Bíi ti Fáráò,

  Wọ́n máa pa run l’Ámágẹ́dọ́nì.

  Gbogbo wa yóò gbà pé

  Jèhófà lorúkọ rẹ.

  (ÈGBÈ)

  Jèhófà, Ọba ayérayé,

  Gbogbo ayé máa rí agbára rẹ,

  Nígbà tóo bá pàwọn ọ̀tá rẹ run,

  Wàá sọrúkọ rẹ di mímọ́.