WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

(2 Sámúẹ́lì 22:1-8)

 1. 1. Jèhófà, Ọlọ́run alààyè mà ni ọ́;

  À ńríṣẹ́ ọwọ́ rẹ

  láyé àti lọ́run.

  Kò sí ọlọ́run tó lè bá ọ́ dọ́gba,

  kò ní sí.

  Ọ̀tá wa yóò ṣègbé.

  (ÈGBÈ)

  Jèhófà ńṣọ̀nà àsálà fólóòótọ́.

  Àwa èèyàn rẹ̀ yóò jẹ́rìí ságbára rẹ̀.

  Ká nígbàgbọ́ àti ìgboyà,

  ká máa wàásù

  Nípa Ọlọ́run ìgbàlà wa,

  ká sì máa yìnín.

 2. 2. Ẹ̀mí mi fẹ́ bọ́, mo ké pè ọ́ Jèhófà,

  “Jọ̀ọ́ fún mi lágbára,

  mo nílò okun rẹ.”

  O sì wá gbọ́ àdúrà àtọkànwá

  tí mo gbà,

  O sì wá kó mi yọ.

  (ÈGBÈ)

  Jèhófà ńṣọ̀nà àsálà fólóòótọ́.

  Àwa èèyàn rẹ̀ yóò jẹ́rìí ságbára rẹ̀.

  Ká nígbàgbọ́ àti ìgboyà,

  ká máa wàásù

  Nípa Ọlọ́run ìgbàlà wa,

  ká sì máa yìnín.

 3.  3. Ohùn rẹ yóò dún bí àrá

  látọ̀run wá.

  Ọ̀tá rẹ yóò páyà;

  àwa yóò kún fáyọ̀.

  Alèwílèṣe ni ọ́, Ọlọ́run wa.

  Aó sì ríi

  Bí wàá ṣe gbà wá là.

  (ÈGBÈ)

  Jèhófà ńṣọ̀nà àsálà fólóòótọ́.

  Àwa èèyàn rẹ̀ yóò jẹ́rìí ságbára rẹ̀.

  Ká nígbàgbọ́ àti ìgboyà,

  ká máa wàásù

  Nípa Ọlọ́run ìgbàlà wa,

  ká sì máa yìnín.